Osun Kidnapping: Àjọṣepọ̀ ọlọ́pàá, DSS, OPC gba ìtúsílẹ̀ àwọn mẹ́wàá tí wọ́n jígbé ní Ọ̀ṣun

Awọn agbofinro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ero mẹwa to ku ninu ero bọọsi ti awọn ajinigbe kan ji gbe nipinlẹ Ọṣun ti di riri nipasẹ ajọṣepọ laarin awọn ọlọpaa, ọmọ ẹgbẹ OPC atawọn oṣiṣẹ agbofinro DSS.

Agbegbe ileto Ajeoku ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe lasiko ti ọkọ wọn fi n lọ si ilu Abuja.

Meji ninu awọn eeyan ọhun lawọn to ji wọn gbe yin ni ibọn.

Awọn marun kan ninu eyi ti mẹta jẹ smọ iya kan naa ni awọn agbofinro kọkọ ri gba pada ki wọn to tun ri marun un miran gba lẹyin ọpọlọpọ wakati ti awsn agbofinro naa si fija pẹẹta pẹlu ibọn lati koju wọn.

Awọn kan ti ọrs naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ajinigbe naa ti wọn funrasi pe wọn jẹ darandaran fulani kskọ tu awọn to n tọ ọmọ lọwọ, awọn arugbo atawọn ọmọ wẹwẹ to wa ninu ọkọ naa silẹ.

Olori ẹbẹ OPC ni ipinlẹ Ọṣun, Deji Aladeṣawẹ ṣalaye fawọn akọroyin pe inu igbo Olua ni imẹsi ile lawọn ajinigbe naa ko awsn ti wọn ji gbe lọ ki wọn to sa asala fun ẹmi wọn nigba tawọn agbofinro koju wọn pẹlu ibọn.