Psychedelic Drugs: Oògùn tó ń mú ni gbàgbé ìṣòro tí wọn ń lò láì bíkítà, tó sì fẹ́rẹ̀ gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó ń lò ó

Àkọlé fídíò, Oògùn tó ń mú ni gbàgbé ìṣòro tí wọn ń lò láì bíkítà, tó sì fẹ́rẹ̀ gbẹ̀mí àwọn èèyàn tó ń lò ó
    • Author, Claire Mawisa
    • Author, Marco Oriunto
    • Author, Nicky Troll
    • Author, Jo Munnik
    • Role, BBC Africa Eye
    • Reporting from, Cape Town & London
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn oogun to maa n mu ki eeyan gbagbe iṣoro rẹ tabi ibi to ba wa, eyii ti wọn n pe ni 'psychedelic drugs' lodi si ofin ni South Africa.

Amọ ọpọ awọn oniwosan n lo o fun eeyan, koda wọn tun n polowo rẹ lawọn ilu bii Cape Town.

Ẹnikẹni ti ọwọ ofin ba tẹ pe o o lo oogun naa tabi ta a le san owo itanran tabi ko fi ẹwọn ọdun mẹẹdọgbọn jura, tabi mejeji.

Ayaworan kan, Stuart Dods jẹ ọkan lara awọn eeyan to ṣetan lati lo oogun naa fun iwosan.

O ti n mura lati lo oogun ọhun fun igba keji niluu kan ti ko fi bẹẹ jina si Cape Twon lati wo awọn arun ọpọlọ kan to n ba finra.

Ṣaaju akoko yii lo ti kọkọ lo awọn oogun kan amọ o gbagbọ pe oogun ti ko ba ofin mu yii nikan lo le tan iṣoro oun.

Ẹni ọdun mẹtalelaadọta naa sọ pe iya oun "jade laye lojiji, o si jẹ akoko to lera julọ.

Lẹyin naa ni ololufẹ mi kọ mi silẹ lẹyin ọdun kan ti iya mi jade laye. Asiko yii gan ni gbogbo nnkan yiwọ."

Pẹlu owo ti iye rẹ jẹ $2,000 (£1,500), eeyan le lo oogun ti wọn n pe ni psilocybin (ti ọpọ tun mọ si 'magic mushrooms) to maa n mu ki eeyan gbagbe ibi to wa tabi ohun to n la kọja.

Awọn ti yoo tọju rẹ sọ pe owo ile atawọn itọju mii tun kun $2,000 ti yoo san fun itọju yii.

Oniruru iwadii lo ti n lọ lọwọ lori bi itọju naa ṣe lagbara to ati bo ṣe n ṣiṣẹ si lati wo arun ọpọlọ amọ awọn onimọ ti kilọ pe itọju naa lewu ti awọn akọṣẹmọṣẹ ko ba si nibi itọju ọhun.

Ọkunrin to fi ẹyin lelẹ lori ibusun pẹlu aṣọ dudu loju rẹ atawọn obinrin meji to tọju rẹ lai oju wọn lede
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Megan Hardy, to juwe ara rẹ gẹgẹ bii oluwosan ti yoo ṣe ṣe iwosan ọgbẹni Dos naa mu iwọn diẹ lara oogun naa ko to bẹrẹ itọju Dods, eyii to ni yoo ran oun lọwọ lati wa ni ipele kan naa ti ẹni ti oun n tọju yoo wa.

Hardy yii mọ pe lilo awọn oogun naa lodi si ofin amọ o ni oun yoo tapa si ofin ọhun lọna to tọ.

Nigba to n dahun ibere lori boya o ni iwe ẹri lati mọ iye iwọn oogun ti yoo fun ẹni to n tọju, o fesi pe fun ọpọ ọdun loun funra oun ti n lo oogun naa, oun si ti mọ bo ṣe n ṣiṣẹ si.

Ọpọ araalu ni South Africa lo ti ni oye nipa awọn oogun naa bayii latari ipolongo ijọba lodi si bi awọn kan ṣe n lo o fun itọju aisan ironu laroju, ibanujẹ ọkan, ibẹru latari ohun buburu to ṣẹlẹ si eeyan, PTSD, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ṣeṣe ki ẹnikan ninu eeyan meji lagbaye ni arun ọpọlọ ki wọn to jade laye gẹgẹ bii iwadii Harvard Medical School ati fasiti Queensland, to n tumọ si pe ọpọ owo gọbọi lo wa nidi itọju arun ọpọlọ.

Ki wọn to bẹrẹ itọju Stuart pẹlu awọn oogun yii, o ni ileeṣẹ wa le ka itọju oun silẹ, Hardy sọ pe asiko to ba wu Dods lo le sọ pe oun ko ṣe mọ

Hardy ni "ti a ba de ipele kan ti o si ri pe o ko nifẹ si itọju naa mọ, iwọ ṣaa sọ fun mi pe o to gẹ!"

Alabaṣiṣẹ rẹ, Kate Ferguson, ti oun naa ti lo oogu ọhun kẹkọọ nipa imọ iṣẹgun.

Nigba ti wọn bẹrẹ, Dods sun lori ibusun kan, wọn fi aṣọ ibora bo ara rẹ, wọn si fi aṣọ dudu kekere kan bo oju rẹ.

Bi oogun naa ṣe bẹrẹ si n ṣiṣẹ lagọ ara rẹ, nigba kan ara rẹ yoo balẹ amọ nigba miran yoo maa gbọn bii ẹni ti giri n mu.

Ọwọ eeyan to gbe oogun to wa ninu awọ dani
Àkọlé àwòrán, Awọn osun ti wọn yoo fi tọju Dods ree
A head and shoulders image of Stuart Dods wearing a grey T-shirt.
BBC
There was no coercion. It was more just me figuring out in that space, do I want to take this?"
Stuart Dods

Bi awọn obinrin mejeji ṣe n jo ewe ni wọn n kọ awọn orin ibiblẹ kan.

Hardy n fi abẹbẹ ti wọn fi iyẹ adiyẹ ṣe fẹ Dods lara, o ni oun n ṣe eyii lati le awọn ohun ti ko dara lara rẹ sọnu.

Lẹyin naa lo fun lawọn oogun MDMA ọhun. Bo tilẹ jẹ pe o ti kọkọ faramọ pe oun yoo gba awọn oogun naa, Hardy tun bere lọwọ rẹ boya o fẹ lati lo oogun ọhun tabi bẹẹ kọ amọ o dahun pe "mi o mọ."

BBC bere lọwọ Dods lẹyin eto naa bo ṣe gba lati lo oogun lasiko ti ko mọ ibi to wa, o dahun pe wọn ko fi agidi mu oun ati pe oun mọ ohun ti oun n ṣe.

A head and shoulder shot of Megan Hardy.
BBC
We're working in ways that the Western mind doesn't understand and can seem scary"
Megan Hardy
Self-styled healer

BBC bere lọwọ Hardy boya oogun naa ko maa pa oun funra rẹ lara lasiko to n tọju Dods, ṣugbọn ko fun wa ni idahun taara.

Awọn iwadii kan ti n lọ lọwọ lati mọ boya lilo awọn oogun naa le kapa awon aisan to maa n ṣe eeyan to ba n ronu ju.

Lọdun 2022, awọn oluwadii ṣayẹwo eeyan 233 to lo oogun 'psilocybin' yii.

Iwadii ayẹwo naa fi han pe eeyan le gbadun to ba lo iwọn 25mg rẹ ti awọn akọṣẹmọṣẹ si n bojuto irufẹ ẹni bẹẹ.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọdun 2025, iwadii ajọ European Medicines Agency lori eeyan 595 fidi rẹ mulẹ pe ẹri ti dantọ gbọdọ wa ki wọn to le maa fun eeyan ni oogun naa lati lo.

Esi iwadii naa tun kilọ pe lilo oogun ọhun lọna ti ko yẹ le yọri si ẹjẹ riru, ati iṣẹ aṣeju fun ọkan, eyii to fi ṣe pataki ko jẹ pe awọn akọṣẹmọṣẹ nikan ni yoo maa fun eeyan ni oogun ọhun lati lo.

Ọpọ orilẹede lagbaye lo ti gbẹsẹle lilo oogun naa amọ awọn eeyan ṣi n lo o lọna ti ko ba ofin mu ni South Africa pẹlu bi wọn ṣe n polowo rẹ lori ayelujara.

Obinrin to duro lẹgbẹ ẹṣin funfun

Lọdun diẹ sẹyin, Sonette Hill to maa n lo irufẹ oogun naa (Ibogaine) fun iwosan awọn eeyan ni oun lo oogun ọhun fun ẹnikan amọ ọrọ bẹyin yọ.

O ṣalaye pe "niṣe lo gba ọfun mi mu, o fẹ gbẹmi mi. Mi o mọ nnkan to ṣadede ba le amọ o fẹ gbẹmi mi."

Wọn maa n lo oogun Ibogaine yii fun ẹni to ba ṣoro fun lati fi awọn iwa buburu kan – bii siga tabi ọti mimu - silẹ, oogun naa si lodi si ofin ni South Africa, ayafi awọn oniṣegun to gba iwe aṣẹ nikan lo le ra.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko fi ofin gbe Hill lẹyin naa, o ti sọ pe oun ko lo oogun naa fun ẹnikẹni mọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun.