South Africa - Adigunjalè fọlé ọga Ọlọpàá ní South Africa

Oga Olopaa Ile South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Adigunjalè fọlé ọga Ọlọpàá ní South Africa

Awọn adigunjale ni wọn ti ṣọṣẹ ni ile ẹni to jẹ ọga agba ajọ ọlọpaa, Khekla Sitole ni orilẹ-ede South Afrika.

Ọkan lara awọn Oga ologun ilẹ naa sọ wi pe, awọn adigunjale naa ko ẹrọ amohun maworan meji lọ lai ba ohunkohun jẹ.

Iṣẹ atunṣe n lọ lọwọ nile ọga agba kọmiṣọna agbofinro ọhun.

Koda, o ni, o dabi ẹni pe iṣẹ atunṣe ti wọn ko i ti pari iṣe rẹ sugbọn ti awọn alọ-kolohunkigbe naa lo anfaani yii.

Ọga ọlọpaa naa ni oun lọ fun ipade ni ile Igbimọ Aṣofin ilẹ naa ni Cape Town lasiko ti awọn adigunjale naa ṣiṣẹ laabi ọhun.

Wahala nla ni eyi ti da si agbada ọga ọlọpaa naa nitori Ijọba ilẹ naa ṣi wa lọrun un rẹ lati mu adinku ba iwa ọdaran ki eyi to tun ṣẹlẹ si oun alara.