Akure Church: Ọlọ́pàá ní kòsí olubi-ọmọ ní ilé ìjọsìn Akure

Oríṣun àwòrán, church site
Oluṣọ Aguntan ti wọn fi ẹsun kan lori pe o ri olubi ọmọ mọlẹ sinu ijọ ti ṣalaye pe irọ funfun balau ni o.
Nigba ti o n fomijomitoro ọrọ pelu ikọ ile iṣẹ BBC Yoruba, Oluṣọ Aguntan naa, Gbenga Akinbiyi ni,oun gangan lo pe Ọlọpaa wa si inu ijọ.
O ṣalaye pe, awọn alagba ijọ naa tẹlẹ lo n pariwo pe iṣẹ iranṣẹ oun kii ṣe ojulowo ki oun to gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Ninu alaye rẹ lo ti sọ pe, fifi aaye silẹ fun ibajẹ lo ṣokunfa ọtẹ ati ibanijẹ naa.
Agbẹnusọ ijọ naa, Ọgbẹni Rotimi Brown ṣalaye pe, aworan Obinrin ni enikan gbe si oju opo kan lati tabuku iranṣẹ ọlọrun naa pe wọn jọ n ṣe wọle wọde.
Ṣe saaju ni ajọ ọlọpa ti yabo ile ijọsin naa lati fi idi ootọ mulẹ lori boya lootọ ni oluṣọ naa ri ẹya ara eniyan mọlẹ sugbọn ti ko si ohun to jọ bẹẹ.
Ninu ọrọ ti Alukoro awọn ọlọpaa, Ọgbẹni Fẹmi Joseph sọ, o ni iwadii ṣi n lọ lori ọrọ naa.
Ọlọpaa ni kete ti wọn ba ti fi ẹnu ọrọ naa ti si bi kan ni wọn yoo jẹ ki ara ilu mọ,sugbọn ti ko i ti i si ifidi mulẹ iru ọrọ bẹẹ.












