JAMB: Àjọ tí ó ń rísí ìdánwò ìgbaniwọlé silé ìwé gíga ti gbé òfin míì síta

jamb

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ohun tuntun ninu idanwo ile iwe giga JAMB ni 2020

Ajọ to n ṣeto igbaniwọle fawọn akẹkọo ile iwe giga gbe amuyẹ tuntun sita fun eto idanwo 2020.

Ajọ ti o wa fun igbani wọle si ile iwe giga ni Naijiria, JAMB, ti pasẹ pe laisi nọmba idanimọ, ko si idanwo fun akẹkọọ lati wọle.

Ajọ yii ti ni dandan lowo ori ni fun gbogbo awọn ti o ba ni lọkan lati ṣe idanwo si ile iwe giga ki wọn o ni nọmba idanimọ naa.

Alukoro fun Ajọ ti o wa fun idanwo igbani wọle naa, Fabian Benjamin, ni o sọ ọrọ yii ni Abuja ni Ọjọru ọsẹ yii.

O ni o se pataki lati gunle irufẹ eto yii lojuna ati dẹkun magomago ninu idanwo igbani wọle naa.

Fabian wa gba awọn ti o ba nifẹ lati kọ idanwo sile iwe giga UTME lati lọ si ọdọ ajọ ti o wa fun fifun ni ni nọmba idanimọ Naijiria. iyẹn NIN ṣaaju ọjọ idanwo.

Adari ẹka ifitonileti fun ajọ JAMB naa ṣalaye pe, gbogbo awọn ti o ti gba nọmba nigba naa ṣaaju asiko ti wọn gba fọọmu tele lọ ṣe atunṣe si fọọmu wọn.

Ninu amọran an rẹ, o ni, ti o ba ni ẹnikẹni ti o ni ṣugbọn ti nọmba rẹ ti sọnu ni ko pada lọ ba ajọ iforukọ silẹ naa tabi ki o tẹ *346# lori siimu rẹ ti o fi silẹ.

Ajọ JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB portal

Àkọlé àwòrán, JAMB

Fabian wa ni orukọ ti iru ẹni bẹẹ ba fi silẹ pẹlu ile iṣẹ ti o n ri si lforukọsilẹ naa ni yoo han ni ọdọ ajọ ti o n ri si eto ldanwo igbaniwọle naa.

O tẹsiwaju pe ti akẹkọọ kọọkan ba ni idiwọ lori orukọ rẹ ki o kọkọ kan si ajọ ti o wa nipa nọmba naa ṣaaju ajọ Jambu.

Bakan naa ni Fabian ṣalaye pe ajọ JAMB ko ni ṣeto iforukọsilẹ nipa akẹkọọ kọọkan lọdun 2020 rara.

O ni ninu nọmba idanimọ Naijiria, NIN ti akẹkọọ kọọkan ba ti gba láti ajọ eleto iforukọ silẹ NIMC naa ni JAMB a ti lọ mu idahunsi ibeere lori ohun ti wọn fẹ mọ nipa akẹkọọ kọọkan.

Àkọlé fídíò, Brazil Yoruba: A n gbé àwọn ère Yorùbá káàkiri- Ọọni ti Ilé Ifẹ