Nigeria Hospitals: Ohun tó yẹ kí ẹ kíyèsí nì wọ́nyí kí ẹ tó gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn

Kọmisọna fun eto ilera ipinlẹ Eko, Jide Idris

Oríṣun àwòrán, @UcheofLagos

Àkọlé àwòrán, O lewu lati ma lo ile iwosan awọn nọọsi abẹ ile

Kii ṣe gbogbo ile iwosan ni ipinlẹ Eko lo le tọju alaisan -Ajọ HEFAMAA.

Ileeṣẹ ijọba to n ṣamojuto awọn ile iwosan nipinlẹ Eko, HEFAMAA ti gbe agadagodo sẹnu ọna ile iwosan ogun nipinlẹ naa, lataari pe wọn ko tẹle ilana ofin.

Ẹni to gbẹnusọ fun iajọ HEFAMAA, Ada Omehu sọ fun BBC pe, awọn ohun to yẹ ko wa ni awọn ile iwosan to gba ontẹ ijọba ko si ni awọn ileewosan naa, ni HEFAMAA ṣe tii pa.

Ada mẹnuba awọn ohun to yẹ ki awọn eeyan maa kiyesi ki wọn to gba itọju ni ile iwosan eyikeyi ti wọn ba lọ.

Ada darukọ awọn nnkan bii oṣiṣẹ to dantọ, irinṣẹ to ba igba mu, agbegbe ti irufẹ ile iwosan bẹẹ wa, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni amuyẹ ile iwosan to dantọ.

O tẹnumọ ọ pe, ki awọn to ba n ṣaarẹ dẹkun lilọ si ile iwosan awọn nọọsi abẹ ile, nitori o lewu.

Nigba to n sọrọ lori awọn amuyẹ ojulowo ile iwosan, Agbẹnusọ ajọ HEFAMAA ni "irufẹ ileewosan bẹẹ gbọdọ ni awọn oṣisẹ to kawe gboye, kiiṣe awọn nọọsi abẹ ile."

Ada ni: "Ile iwosan bẹẹ tun gbọdọ ni, ile oogun, yara ti wọn ti n ṣe ayẹwo ẹjẹ ati ẹya ara, pẹlu awọn irinṣẹ igablode."

Bẹẹ lo tun ṣalaye pe ile iwosan to ba wa ni agbegbe ibi idalẹsi kii ṣe ojulowo ile iwosan rara nitori ẹgbin ko faaye gba ilera pipe.

Bakan naa lo sọrọ lori ileewosan ogun ti wọn ti pa kaakiri ipinlẹ Eko pe HEFAMAA gbe igbesẹ yii lati daabo bo awọn olugbe ipinlẹ Eko ni.

Àkọlé fídíò, Brazil Yoruba: A n gbé àwọn ère Yorùbá káàkiri- Ọọni ti Ilé Ifẹ