Ilé ẹjọ́ gba béèlì Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adájọ́ tó ń dá ẹ́jọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Sẹ́netọ̀ tó ń sojú ẹkùn ìdìbò Ìwọ̀-oòrùn ìpínlẹ̀ Kogi, Dino Melaye ti gba onídùró rẹ̀.
Adájọ́ Nasir Ajana tó dárí bíbojú wo ìwe onídùró náà tí wọ́n fi ránsẹ́ níwájú ilé ẹjọ́ gíga ti ìlú Lokoja dá ẹjọ́ rẹ̀ lórí àrídájú tó wà nínù onídùró náà gẹ́gẹ́ bí agbẹjọ́rò rẹ̀, Agbẹjọ́rò àgbà Olóyè Mike Ozekhome se fi sọwọ́ sí ilé ẹjọ́.
Ìwé onídùró náà sọ wí pé ó ní se pẹ̀lú bí wọ́n se ti Dino mọ́le láti ọjọ́ yìí, lèyí tó ní ó le sàkóbá fún ìlera rẹ̀.
Ó ní wọn ò rí àrísá pé bí wọ́n bá gba onídùró rẹ̀, yíò sá lọ. Nítorí náà, Ajana gba onídùró Melaye pẹ̀lú mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà.
Ṣáájú, ilé ẹjọ gíga tíó kalẹ̀ sí Lokoja ti kọ́kọ́ sún ìdájọ́ lórí gbígba onídùró fún Dino èyí tí agbẹjọ́rò rẹ Amofin àgbà Mike Ozekhome gbé wà.
Ìdájọ tó wáyé lónìí ṣẹlẹ láì sí Dino ní ilé ẹjọ́. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọwọ ni pé ó ń gba ìtọ́jú ní ile Ìwòsàn National Hospital Abuja.









