Nollywood: Ẹ wo díẹ̀ lára ohun tó ṣelẹ̀ lágbo òṣèré tíátà Yollywood láàrin ọ̀sẹ̀ yìí

Oríṣun àwòrán, others
Ọpọ ohun aridunu lo ṣẹlẹ laarin ọsẹ yii laarin awọn oṣere tiata Yollywood.
Bi awọn kan ṣe n fọmọ fọkọ, lawọn mii n ṣọjọ ibi, bẹẹ lawọn mii n bimọ tuntun.
1. Taiwo Hassan ṣojọ ibi
Taiwo Hassan, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ogogo jẹ agba ọjẹ ninu iṣẹ tiata Yoruba Yinka Quadri: Mo dúpẹ́ pé Ogogo jẹ́ ọ̀rẹ́ mi!.
Wọn bi Ogogo ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa ọdun 1959, o si bẹrẹ iṣe tiata ni ọdun 1981.
Laarin ọsẹ yii ni agba oṣere yii pe ẹni ọgọta ọdun lorilẹ alaye.
Opọ awọn akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ tiatia lo n ki ni mẹsan mẹwa lori itakun ayelujara.
2. Toyin Adegbola
Lara awọn to dantọ ninu agba oṣere naa ni Toyin wa, ki si ṣe ọmọde ninu iṣẹ tiata Yoruba.
Aṣẹwo to re Mẹka ni ọpọlọpọ awọn ololufẹ Toyin mọọ si.
Ọjọ Satide to kọja ni Toyin fi ọmọ fọkọ nilu Ibadan, igbeyawo naa si dun, gbọngbọn kan si pẹlu.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ọpọ oṣere Yollywood bi Mr latin, Dayo Amusa, Foluke Daramola Salakọ, Femi Adebayo, Faithia Balogun ati bẹbẹ lọ, lo yẹ Toyin si nibi igbeyawo ọhun ti K1 the Ultimate, King Wasiu Ayinde Marshall si kọrin nibẹ.
3. Funke Akindele
Ọjọ iṣẹgun ọsẹ yii ni awọn to n tẹlẹ Funke lori itakun Instagram rẹ pe miliọnu mẹsan an.
Lẹyin eyi lo fi ẹmi imoore han si awọn ololufẹ rẹ, ti awọn naa si n fesi pe wọn nifẹ si iṣẹ rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
4. Yinka Ayefele
Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe Ọlọrun fi ibẹta ta Yinka ati ati iyawo rẹ Temitope lọrẹ laipẹ yii Yinka Ayefele di bàbá ìbẹta.
Laarin ọsẹ yii ni Yinka fi oju awọn ọmọ naa lede lori ẹrọ ayelejujara.

Oríṣun àwòrán, @others
Bi awọn kan ṣe n ki ni mẹsan mẹwaa ni awọn miran n fi ọla rẹ tọrọ, ti wọn si n gbadura pe ki Eledua fun awọn naa ni ọmọ alubarika.
5. Tope Alabi
Tope jẹ olorin ẹmi ti awọn ọpọ eeyan mọ kaakiri nilẹ yii ati loke okun.

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi
Aarin ọsẹ yii ni Tope ṣe ọjọ ibi rẹ, leyi to fi pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta laye.
Wọn bi Tope Alabi lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa ọdun 1970 ni ipinlẹ Eko.














