Ethiopia: Ìjà ẹ̀sìn àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà sọ èèyàn 78 dèrò ọ̀run ni Ethiopia

Rogbodiyan lorilẹ-ede Ethiopia

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa ti fi ofin mu irinwo eeyan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣelẹ naa

Eeyan mejidinlọgọrin lo ti dero ọrun lorilẹ-ede Ethiopia lẹyin ifẹhonuhan to waye ni awọn agbegbe kan lorilẹ-ede ọhun.

Adari igbimọ ijọba orilẹ-ede naa, Abiy Ahmed sọ fun awọn oniroyin pe awọn eeyan ọhun jẹ Ọlọrun nipe latari wahala to ṣelẹ latari ifẹhonuhan naa.

Kete lẹyin wahala naa ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ orilẹ-ẹde naa ti fi pampẹ ofin mu irinwo eeyan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu biba duklia jẹ ati gbigbẹmi awọn eeyaan.

Ifẹhonuhan naa bẹrẹ lẹyin ti gbajumọ ajafẹtọ ọmọniyan kan lati ẹya Oromo, Jawar Mohammed sọrọ loju opo Facebook rẹ pe ijọba n fi ẹmi oun wewu lẹyin to yọ awọn adabo rẹ kuro.

Sugbọn ijọba ti fesi pe irọ pata ni ẹsun ti Jawar fi kan an.

Alukoro adari igbimọ ijọba, Billene Seyoum sọ pe, rogbodiyan naa ni ọwọ ẹlẹyamẹya ati ẹsin ninu, leyi to mu ko burẹkẹ.

Ajọ ọlọpaa ni agbegbe Oromia to jẹ agbegbe ti iṣẹlẹ naa pa lara julọ sọ ṣaaju pe eeyan mejidinlaadọrin lo kọkọ jẹ Ọlọrun nipe.

Àkọlé fídíò, Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil