Nollywood: Taiwo Hassan, akọni òṣèré Yollywood tó jẹ́.....

Oríṣun àwòrán, @Ogogo
Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n ki agba oṣere Taiwo Hassan ku oriire ọgọta ọdun lori oke eepẹ loni.
Yinka Quadri to jẹ ọrẹ ti wọn ti jọ n ṣere tipẹtipẹ naa kii pe ọrẹ to yatọ ni Ogogo jẹ
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Opolopo awọn ololufẹ BBC naa n gboriyin fun Ogogo Kulodo ti wọn si n sọrọ nipa awọn ere Taiwo Hassan ti wọn gbadun julọ loju opo BBC News lori facebook.



Taiwo Hassan, akọni òṣèré Yollywood tó jẹ́.....
Wo ǹkan márùn ún ti ò kò mọ̀ nípa Taiwo Hassan, Ogogo ọmọ kulodo tó n ṣeré Yorùbá.
A bi Taiwo Hassan ti gbogbo eeyan mọ si Ogogo ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1959.
Ilu Ilaro ni ipinlẹ Ogun ni guusu iwọ oorun Naijiria ni ati bi Ogogo ọmọ Kulodo.

Oríṣun àwòrán, @Ogogo
Oṣere ti igba oju mọ ni Taiwo Hassan, o ti ṣe awọn ere to lokiki bii Owo Blow, Sababi, Ibinu elewọn, Atitẹbi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Odindin ọdun mẹtala ni Taiwo Hassan fi ṣiṣẹ pẹlu ẹka to n mojuto omi ẹrọ ni ipinlẹ Eko.
Odun 1994 ni Ogogo fẹyinti kuro lẹnu iṣẹ Oba ipinlẹ Eko ko too gbajumọ ere ṣiṣe ni ẹkunrẹrẹ.
Taiwo Hassan lọ sile iwe alakọbẹrẹ Christ Church School nilu Ilaro.
O tun ló sile iwe Yaba Technical College nibi to ti kọ ẹkọ nipa ọkọ titunṣe.
Ogogo fẹ obinrin meji ọtọọtọ.
Taiwo Hassan bi ọmọbinrin mẹta ati ọmọkunrin kan.
- Orìlẹ-èdè mẹrindínlọgbọn tí ọmọ Nàìjíríá lè wọ̀ láì ní àṣe ìwé ìgbélùú
- À ṣé olóòrùn ni ayálégbé mi tó ń fojóojúmọ́ ṣakọ lórí ayélujára- Onílé Lisa Li
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ṣàwárí agolo akẹ́rù tó kún fún ẹja àti oúnjẹ tó ti díbàjẹ́
- Kogi Prison: Aráàlù tẹ́ẹ bá ní ìròyìn nípa àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sá lọ, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún wa
Odun 1981 ni Taiwo Hassan bẹrẹ iṣẹ ere ṣiṣe ni kete to bẹrẹ iṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko.
Ogogo ni idi ti oun fi n duro deedee bi ọmọkunrin ni ere idaraya ẹṣẹ kíkàn ti oun gbadun lati maa ṣe fi daraya.
Bakan naa lo tun ni oun fẹran lati maa gbọ orin paapaa ti awọn ọdọ iwoyi to ba mọgbọn dani
Ogogo jẹ ọkunrin ti o ni awọn iwa kan to yaa sọtọ lagbo oṣere.
Ninu ifọrọwerọ kan lo ti ṣalaye pe oun kii fẹnuko obinrin lẹnu ninu ere nitori ko si lara abuda adamọ oun.
Ogogo ni oun ko fi bẹẹ fẹran lati maa ṣe ipa ololufẹ to n fi ifẹ han ni gbangba ninu ere agbelewo.
















