Níbo ni ọ̀rọ̀ dé lórí àwọn aṣọ́gbó ọba márùn-ún táwọn agbébọn pa ní ìpínlẹ̀ Oyo?

Aworan awon agebbọn to gbe ibọn dani, bomu.Awọn kan duro ninu ọkọ, awọn kan si duro siwaju ọkọ.

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fidi ẹ mulẹ, pe ọwọ ofin ti ba eeyan meje ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu pipa marun-un lara awọn aṣogbo ọba ipinlẹ Oyo (Old Oyo National Park)to wa lagbegbe Oloka, loṣu Kiini, ọdun 2026.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Olayinka Alayande lo fidi ẹ mulẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta, ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Kiini pe eeyan meje lo ti wa lahamọ ofin bayii lori ipaniyan ati ikọlu naa.

Alayande sọ pe ikọ ẹlẹni mẹwaa ni awọn agbebọn to ya bo igbo ọba naa lọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ lo ni wọn ṣe ikọlu naa.

"Lẹyin atẹjade akọkọ ti a fi kede ikọlu awọn agbebọn si igbo ọba ipinlẹ Oyo to wa lagbegbe Oloka, nijọba ibilẹ Oriire, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fẹẹ fi to gbogbo eeyan leti, pe a ṣe aṣeyọri nla pẹlu bi a ṣe ti mu eeyan meje ninu ikọ ẹrujẹjẹ ẹlẹni mẹwaa naa, titi kan ẹni ti wọn pe ni olori ikọ naa, ti wọn kọlu awọn oṣiṣẹ igbo ọba National Park," Alayande ṣalaye.

O ni ṣaaju ni awọn ti mu mẹta ninu awọn afurasi apaayan naa, orukọ wọn bo ṣe pe e ni: Mohammed Dangi, Abubakar Abdullahi ati Sheu Usman.

''Awọn mẹta tọwọ kọkọ ba lo jẹ ka tun ri mẹrin miran mu, wọn jẹwọ fun wa''

Ni itẹsiwaju alaye Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo nipa bi ọwọ ṣe ba awọn afurasi to di meje bayii, o ni awọn mẹta akọkọ lo ṣọna bi awọn mẹrin yii naa ṣe bọ sọwọ.

" Awọn afurasi naa jẹwọ fun wa pe awọn lawọn wa nidii ikọlu ọhun, wọn si ṣalaye fun wa nipa ọmọ ẹgbẹ mẹwaa ti I ṣe ikọ akọluni naa.

" Wọn sọ fun wa pe awọn mẹwaa ni wọn gun ọkada marun-un wa ti wọn si ṣe ikọlu ọhun.

" Ero ọkan wọn latilẹ ni lati fipa tu awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti a mu ṣaaju silẹ, awọn ti won wa ni ahamọ awọn aṣogbo ninu igbo ọba fun ẹsun ọdaran ọlọkan-o-jọkan, eyi ti wọn ri ṣe lasiko ikọlu naa."

Nigba to n darukọ awọn mẹrin ti ọwọ ijọba ṣẹṣẹ ba bayii, DSP Alayande sọ pe orukọ wọn ni : Toro Malami, Usman Alhaji Ummaru, Laolo Muhammadu ati Usman Alhaji Isah.

O ni ibuba wọ́n ti wọn fi ara pamọ si kiri ni awọn ti hu wọn jade lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn wọnyi naa ti n fọwọsowọpọ pẹlu ọlọpaa nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ti ọwọ ko ti I ba mu.

Tẹ o ba gbagbe, ikọlu buruku naa waye nigba ti ódun tuntun yii ṣẹṣẹ bẹrẹ, ọjọ kẹfa ninu oṣu akọkọ ọdun 2026 ni wọn fi alẹ boju yabo igbo ọba naa, wọn si yinbọn pa aṣogbo marun-un, wọn too sa wọgbo lọ leyin rẹ.

Awọn agbébọn ṣèkọlù sáwọn aṣọ́gbó ọba, pa èèyàn mẹ́rin nípìnlẹ̀ Oyo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni a ti kọkọ mu iroyin wa pe awọn agbebon ṣe ikọlu si ọfiisi ajọ asọgbo ọba to wa ni agbegbe Oloka, ijọba ibilẹ Orire nipinlẹ Ọyọ.

‎‎Ikolu naa to waye ni nnkan bii aago mẹsan alẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹfa, oṣu Kiini, ọdun 2026 ṣokunfa iku aṣọgbo mẹrin, ti ẹnikan si wani ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun amọ ti ẹni naa pada ku.

Iroyin ni awọn agbebọn to ṣekọlu sawọn aṣọgbo naa ko gbogbo ìbọn ti wọn n lo lọ.

‎‎‎Atẹjade kan ti agbenuso ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi lede, Ayanlade Olayinka fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ṣalaye pe ile iṣe ọlọpaa ati awọn ajọ to niṣe pẹlu aabo ilu ni wọn ti wa ninu igbo ọba ọhun lati ṣawari awọn agbebon to ṣekọlu ọhun.

‎Olayinka tesiwaju pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Femi Haruna pẹlu awọn olori ileeṣẹ aabo to wa nipinlẹ Ọyọ ti n lọ si agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni igbesẹ yii lo n waye lati ri wi pe alaafia pada si agbegbe naa lojuna ati ri daju pe aabo wa fun gbogbo awọn eeyan ati dukia lagbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Atẹjade naa wa rọ awọn ara ilu Oloka lati fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ki ọwọ le tete tẹ awọn afurasi agbebọn naa.

‎ Ọkan lara olugbe agbegbe naa to ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye wi pe mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ asọgbo ọba lọ jade laye, ti ẹnikan yooku si wa ni ile iwosan nibi to ti n gba itọju.

‎O sọ pe gbogbo ilu naa lo ti dahoro, ti gbogbo awọn araalu ti sa kuro nile wọn tan.

O fi kun pe to fi mọ Baalẹ ilu naa lo ti kuro ninu ilu.

Ikọlu yii ni yoo jẹ akọkọ iru rẹ ni agbegbe yìí.

Lẹyin naa ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede pe oun maa ri pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko waye mọ to si tun jẹjẹẹ lati fun awọn ẹbi ti wọn padanu eeyan wọn ni owo.