Kí lohun tí Kunle Afolayan sọ nípa Funke Akindele tó fa ariwo lórí ayélujára?

Oríṣun àwòrán, Kunle Afolayan/Funke Akindele/ Facebook
Bo ti wu ka jọ maa siṣẹ kan naa to, igbiyanju ẹda lori ati la, lowo lọwọ, yatọ sira wọn.
Eyi ni ohun to n fa ariwo lori ayelujara bayii, nipa ọrọ kan ti gbajumọ oṣere, Kunle Afolayan sọ nipa oṣere ẹgbẹ rẹ, Funke Akindele atawọn onitiata mi-in ti wọn maan gbe iṣẹ wọn lọ si sinima.
Lori eto kan to waye laipẹ yii, ti wọn pe ni The Lagos Business of Film Summit, ni wọn ti beere lọwọ Afolayan pe ki lo de ti ki i saba gbe iṣẹ rẹ lọ si sinima bii awọn ẹgbẹ rẹ yooku.
Nigba naa ni oṣere ti baba rẹ, Adelove, naa jẹ gbajugbaja oṣere nigba aye rẹ ṣalaye pe ki I ṣe pe oun ko nifẹẹ si gbigbe iṣẹ oun lọ si sinima:
"Mo wa lara awọn eeyan to kọkọ bẹrẹ si i gbe ere lọ si sinima, koda ijo jijo, emi ni mo bẹrẹ rẹ. Mo jo ni London gan-an, ki i ṣe ni nile nikan.
"Mo fẹ ṣe fiimu kan, ti o ba le fi da mi loju pe mi o nilo lati jo ki n too ta fiimu naa, o ya. O maa n nira gan-an."
Kunle Afolayan tẹsiwaju pe oun ko fẹ daamu ara oun, o ni o yẹ ki awọn ilana miran wa ti ko ni i jẹ eyi to n fun eeyan ni wahala bii eyi, ti awọn yoo ta fiimu lai padanu gbogbo okun ati agbara lori iṣẹ naa.
"Emi o mọ bi Funke ati awọn bẹẹ yẹn ṣe n ṣe e, ti wọn n gbe iru nnkan bayii jade, ti wọn n ṣe ọjọ kan, aṣọ kan lori itage, haa, emi o le ṣe e."
Bẹẹ ni Kunle Afolayan wi.
O ni oun ni itan nilẹ lati bii ọdun mẹrin to si wu oun lati gbe jade, ṣugbọn ọna miran ni oun n wa fun un.
'Mi o fẹ biliọnu kan naira sinima ti mi o ni I le gba miliọnu mẹwaa lorii rẹ'
Ninu fidio mi-in, nibi ti Kunle Afolayan ti n sọrọ lori ifigagbagba lo ti ṣafikun ọrọ nipa gbigbe fiimu lọ si sinima.
Fidio naa ṣafihan Afolayan pẹlu Ibrahim Chatta toun naa jẹ gbajumọ oṣere, nibi ti Afolayan ti n sọ pe oun ko ba Chatta figagbaga nitori abule fiimu ti oṣere naa kọ siluu Oyo.
O ni awon ko kuku jọ ṣe nnkan kan naa pọ.
Kunle Afolayan sọ pe:
"Mi o fẹ biliọnu meji naira, mi o tiẹ fẹ biliọnu kan naira gan-an ni sinima ti mi o ni I le gba miliọnu mẹwaa."
O tẹsiwaju pe iṣẹ toun ati Chatta n ṣe da lori gbigbe ohun ti awọn irandiran ti ṣe kalẹ ga, ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu a n figa gbaga.
Ọrọ ti Kunle sọ yii lo ti bẹrẹ si i mu oriṣiisii awuyewuye wa, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe niṣe ni oṣere naa n fi awọn Funke Akindele, Toyin Aimakhu atawọn miran to n gbe fiimu lọ si sinima ṣe yeyẹ.
Wọn ni ṣe irọ waa ni biliọnu meji ti awọn n gbọ pe Funke Akindele n pa ni sinima ni, abi Kunle wulẹ n fi oṣere naa ṣe ẹfẹ.
Beẹ ni awọn miran n sọ pe ootọ ọrọ wa ninu ohun ti agba oṣere yii sọ, wọn ni o le ma jẹ gbogbo owo ti araalu n feti gbọ pe wọn n pa ni sinima naa lo n tẹ wọn lọwọ.
Ṣaa, ọrọ naa ṣi n ja ran-in lori ayelujara pẹlu ero araalu ti ko jọra wọn le e lori.
Funke Akindele fèsì
Ninu ohun ti Funke Akindele kọ si oju opo X rẹ lẹyin ọrọ ti Kunle Afolayan sọ, ọpẹ ati ẹmi imoore lo fi han si Oluwa lori iṣẹ rẹ to ti n ba a bọ lati ọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin.
Loju opo naa ni Funke ti fi ọpẹ fun Ọlọrun fun agbara, ọgbọn, imọ ati oye to fi gbe fiimu rẹ tuntun ti wọn lo pa biliọnu naira jade.
Oṣere naa dupẹ pe oun ni anfaani lati ṣafihan iṣẹ ọhun, bẹẹ lo ni kawọn eeyan tun tu jade lọ si sinima lati wo o si i.
Koda, iṣẹ naa ko duro ni sinima ilẹ yii nikan bo ṣe wi, Funke ni o tun wa loke okun bii UK ati Ireland.
"Ohun ti mo fẹran lati maa ṣe ni tootọ ree, mo si dupẹ fun anfaani lati ṣafihan rẹ pẹlu awọn ẹbi mi.''
Bẹẹ ni apa kan ọrọ ti Funke Akindele kọ soju opo rẹ naa ka.
Eyi ni ọpọ eeyan fi n sọ pe bo tilẹ jẹ pe iṣẹ kan naa ni oun ati Kunle Afolayan n ṣe, ti wọn si jọ jẹ agba onkọtan, sibẹ, ilana iṣẹ ati ọna ti kaluku n gba ri owo rẹ ko jọra wọn.


























