Wo nǹkan mẹ́ta tó le ṣokùnfà kí ẹ̀jẹ̀ máa wà nínú ìgbọ̀nsẹ̀ rẹ

Obìnrin tó da orí délẹ̀ tó fi ọwọ́ bojú

Oríṣun àwòrán, Daniel de la Hoz/ Getty Images

    • Author, Redacción
    • Role, BBC News Mundo
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rírí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ tó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn.

Lọ́dọ̀ àwọn èèyàn kan tí wọ́n bá ti rí ẹ̀jẹ̀ báyìí, ohun tó máa ń wá sọ́kàn wọn ni pé jẹ̀díjẹ̀dí ló fà á.

Fún àwọn míì ó máa ń dá ìbẹ̀rù sí wọn lọ́kàn pé kó má jẹ̀ ẹ́ pé àwọn ti ní àìsàn jẹjẹrẹ ìdí.

Ẹ̀wẹ̀, ìwádìí fi hàn pé onírúurú nǹkan ló le fa kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́ tí wọ́n sì le le ju ara wọn lọ.

Fermín Mearín, adarí ẹ̀ka tó máa ń rí sí bí oúnjẹ ṣe ń dà nínú ní ilé ìwòsàn Teknon Medical Centre ṣàlàyé fún BBC Mundo lórí àwọn ohun tó le ṣokùnfà kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́.

Àwòrán tó ń ṣàfihàn ìdí yíyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìdí yíyọ: Tí ìdí èèyàn bá ń yọ, ó máa ń fa kí ẹ̀jẹ̀ wà nínú ìgbẹ́ tí èèyàn bá ya.

Èyí sábà máa ń ṣe àfihàn pé ẹ̀jẹ̀ náà ń wá láti abẹ́ tó sì lè jẹ́ pé ẹnu ìdí ló fà á.

Kò rọrùn láti rí jẹ̀díjẹ̀dí pẹ̀lú ojú lásán àyàfi pẹ̀lú ṣíṣe àyẹ̀wò láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdí tàbi títí ọwọ́ bọ inú ìdí gan-an.

Aparato digestivo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àìsàn inú: àìsàn inú èyí tó le mú kí apá kan nínú wú le jẹ́ "colitis ulcerosa" tàbí àìsàn tí wọ́n ń pè ní "Crohn disease".

Mearín sọ pé yàtọ̀ sí inú wíwú, àìsàn yìí le ṣokùnfà ìgbẹ́ gbuuru àti kí inú máa dun èèyàn.

Ó ní àìsàn yìí sábà máa ń ṣe àkóbá fún ilé ìgbẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Crohn disease tún máa ń ní ipa lórí ìfun.

Ó ní fún àwọn tó bá ní àìsàn báyìí, ìgbẹ́ wọn ma máa dúdú tàbí kó máa pọ́n bí ẹ̀jẹ̀.

Ìgbẹ́ dúdú: Lọ́nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, tí ìgbẹ́ èèyàn bá ń dúdú, tó sì ń lẹ̀pọ̀ mọ́ ara wọn, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ń da ẹ̀jẹ̀ láti inú.

Fún irúfẹ́ èyí, onítọ̀hún máa nílò láti ṣe àyẹ̀wò tí wọ́n ń pè ní 'gastroscopy' láti fi mọ̀ bóyá ẹ̀jẹ̀ náà kìí ṣe ọgbẹ́ inú tàbí 'duodenum'.

Àwòrán ẹ̀yà ara èèyàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọ́pọ̀ ìgbà rírí ìgbẹ́ nínú ẹ̀jẹ̀ kò túmọ̀ sí pé nǹkan tó lágbára ló ń ṣe èèyàn.

Ṣùgbọ́n tí ẹ̀jẹ̀ náà bá dúdú, tó sì ń wà lára ìgbẹ́, ó le jẹ́ láti ilé ìgbẹ́ tàbí láti ẹ̀yà ara míì.

Fún irú àwọn tó bá rí báyìí, àwọn dókítà máa ń sọ pé kí èèyàn ṣe àyẹ̀wò tí wọ́n ń pè ní colonoscopy láti fi mọ̀ bóyá jẹjẹrẹ ìdí, polyps, tàbí vascular lesions ló ń ṣe ẹni náà.

Àwọn orílẹ̀ èdè kan máa ń ṣe àyẹ̀wò jẹjẹrẹ ìdí fáwọn èèyàn tó bá wà láàárín ọjọ́ orí kan.

Wọ́n máa ń lo àwọn ìgbẹ́ tí ẹ̀jẹ̀ bá yí láti fi mọ̀ bóyá jẹjẹrẹ ìdí wà níbẹ̀.

Tí wọ́n bá rí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ èèyàn, wọ́n máa ní kí onítọ̀hùn tún lọ ṣe àwọn àyẹ̀wò míì si láti fi mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gangan.

Mearín ní ọ̀pọ̀ ló máa 'bẹ̀rù nígbà tí wọ́n bá ń lọ fún àyẹ̀wò ṣùgbọ́n ni nǹkan tó ń ṣe wọn kìí lágbára lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe àyẹ̀wò tán.

Fún ẹni tó bá ti lé ní àádọ́ta ọdún tàbí ẹni tí èèyàn kan bá ti ní àìsàn jẹjẹrẹ ìdí ní ìdílé wọn rí, àwọn dókítà máa ń ní kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò jẹjẹrẹ ìdí.

Bákan náà ni àwọn oúnjẹ kan le mú kí ìgbẹ́ èèyàn dúdú.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìgbàkígbà tí o bá ti rí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbẹ́ rẹ, ó ṣe pàtàkì láti tètè gba ilé ìwòsàn lọ láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gangan.