Ooni Adeyeye Ogunwusi: Ọọ̀ni tí a bí ní agogo kan géérégé bí àsọtẹ́lẹ̀, táwọn òbí rẹ̀ kò sí fọwọ́ kàn-án lórí láti'gbà èwe

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi jẹ eekan lara awọn ọba alaye lagbaaye. Ori apeare Ọọni si jẹ eyi ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin, ti ọpọ si mọ gẹgẹ bii alakoso aṣa ilẹ Yoruba.
Lọdun 2015 ni Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi jọba, oun si ni Ọọni kọkanlelaadọta.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Baba to bi Ooni Ogunwusi, Ọba John Olurọpo Ogunwusi, ṣalaye pe ki wọn too bi Kabiyesi naa ni asọtẹlẹ ti jade pe okiki rẹ yoo kan kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
O ni wolii kan lo tọ awọn obi rẹ wa pe ọmọ kan n bọ ti wọn yoo bi ni deede agogo kan geerege, pe okiki ọmọ naa yoo tobi to bẹẹ gẹẹ.
O ni ilu Ibadan ni oun ati iya rẹ wa nigba naa ti wolii kan kọja to si sọ fawọn pe awọn maa bi ọmọ kan.
Baba Ooni Adeyeye sọ pe ki i ṣe aarọ tabi ọsan ni wọn maa bi ọmọ naa ni wolii wi. O ni agogo kan oru geerege ni wọn yoo bi ọmọ naa, ati pe agogo kan naa ko ni din ni iṣẹju marun-un ko si ni le ni iṣẹju marun un.

Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Lara awọn ohun miran to jẹ kayeefi nipa ibi Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni bi Baba baba rẹ ti ṣe ti kilọ fun awọn obi rẹ ni kete ti wọn bi i, pe wọn ko gbọdọ fi ọwọ gba a lori o "nitori pe ori ade lo gbe wa saye".
Lati kekere yii naa si ni Baba baba rẹ yii ti maa n pe e ni Adeyẹye Ọọni.
Bi o tilẹ jẹ pe ọmọ ọkunrin mẹta ni awọn obi rẹ bi, Ọọni Adeyẹye Ogunwusi ni aburo wọn, oun nikan lo fi ifẹ han si ipo naa.
Lati igba kekere rẹ titi de asiko to jẹ ọba lo ti n gbaradi fun igba ti yoo ba ya lati jẹ ipe ati dari ilẹ Yoruba.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 1974 ni wọn bi Ọoni Adeyeye Ogunwusi si idile ọlọba Giesi, Ile Ife.
Oniṣiro owo tẹlẹ ni, o si tun ni imọ nipa imọ ẹrọ


























