Bolivia: Ẹ̀rù kò bà mí láti padà sí Bolivia- Evo Morales

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Evo Morales to tukọ orilẹ-ede Bolivia fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti kede pe oun n pada bọ wa sile.
Aarẹ Evo lo sa kuro nile nigba ti ifẹhonuhan nla bẹ silẹ ni Bolivia ti ẹmi awọn eeyan kan si sọnu lẹyin idibo wọn to kọja Aàrẹ, igbákejì aàrẹ àti aàrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ̀wé fipò sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà
Lọjó kan ṣoṣo ni Aarẹ Morales ati igbakeji rẹ ati aarẹ ile igbimọ aṣọfin ilẹ naa kọwe fipo silẹ Ẹ wo àwọn ààrẹ tí ikọ̀ ọmọ ogun ti gba ìjọba lọ̀wọ̀ wọn
Iroyin ni o kere tan eniyan marun un lo ti doloogbe bayii nibi ikọlu laarin awọn agbofinro ati awọn alatilẹyin Ogbeni Morales.
Agbegbe Cochabamba ni wahala yii ti pọju nitori ibẹ lawọn alatilẹyin Morales pọ si julọ.
Aarẹ ana Evo Morales to ti n ṣe atipo ni Mexico ti ni oun n pada bọ wa sile laipẹ nitori pe ile baba ọmọ ko yẹ ko maa ba ọmọ lẹru.










