Akinyele: Ẹ wo àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí Alexander Akinyele ṣo kọ́lọ́jọ́ tó dé

Oríṣun àwòrán, facebook/Alex Akinyele
Ole ko ni ja agba ko ma ṣe e loju firi.
Alexander Akinyele jẹ ẹni to fẹran lati maa sọrọ lori ẹrọ ayelujara ki ọlọjọ to de.
Ki alagba yii to papoda lo ti n sọrọ lori opo ikansiraẹni lori itakun agbaye pe, oun ko bẹru iku.
Nigba mii, Akinyele a sọrọ lori awọn aṣẹyọri to ti gbele aye ṣe, nigba miran ẹwẹ, Akinyele a sọrọ lori ilera rẹ.
Ẹ wo diẹ lara awọn ohun ti Alex Akinyele fi lede lori ẹrọ ayelujara ko to jade laye.
Baba ni oun ko bẹru iku nibi ti oun baa de lasiko yii, nitori naa
Ṣaaju ni Baba ti ni oun ti gbadun aye oun daadaa nigba ti ahesọ jade nipa iku rẹ lọdun to kọja
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 3
Nigba ti Akinyle pe ọdun kọkanleọgọrin ọdun lori oke eepẹ lo n fayọ rẹ han pe iya rere ni Juliana to bi oun

Oríṣun àwòrán, @akinyele
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 4

Oríṣun àwòrán, @akinyele

Oríṣun àwòrán, facebook/Alex Akinyele
Akinyẹle tun ranti ajóṣepọ oun ati akọnimọọgba Clemens Westerhof ṣaaju iku rẹ
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alex Akinyele minisita àná to dolóògbé

Oríṣun àwòrán, facebook/Alex Akinyele
Wọn bi Alexander Opeyemi Akinyele lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹrin, ọdun 1938, ni ilu Ondo, ni ipinlẹ Ondo.
Lẹyin eyi o lo tun lọ lọ si St. Andrews College ni nilu Oyo, nibi to ti kawe gboye gẹgẹ bi olukọ.
Akinyele lọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ All Saints School ni ilu Ondo, lẹyin naa lo tẹsiwaju ninu ẹkọ girama ni Gboluji Grammar School, ni Ilẹ Oluji, lẹba ilu Ondo.

Oríṣun àwòrán, facebook/Alex Akinyele
Ni ọdun 1967, Akinyele ṣiṣẹ ni ileeṣẹ ijọba to n risi wọlewọde orilẹ-ede ni ipinlẹ Eko.
Ipinlẹ Eko yii kan naa lo ti ṣe iṣẹ miran pẹlu ẹgbẹ alarokọ to kọ itan "Village Headmaster" to di fiimu agbelewo lori ikanni ileeṣẹ NTA lọjọ naa lọhun.
Oun ni minisita tẹlẹri fun ọrọ iroyin, lẹyin naa lo di alaga fun ajọ ere idaraya orilẹ-ede yii.
Lẹyin naa, Akinyele tun ṣiṣe goke agba ni ileeṣẹ ijọba to n risi wọlewọde, to si di agbẹnusọ fun ẹka ileeṣẹ ọhun.
O ṣe iṣẹ ni ileeṣẹ wọlewọde naa titi di ọdun 1978 to darapọmọ ileeṣẹ to n ṣe ohun eelo ataraṣe.
O paarọ orukọ ẹgbẹ agbabọọlu agba ti Naijiria lati Green Eagles si Super Eagles.
Akinyele jẹ ọkan pataki lara awọn to gbe owo kalẹ ti wọn fi da ileeṣẹ iroyin Newswatch silẹ, o si ko ipa pataki fun idagbasoke ileeṣẹ ọhun ki ijóba to tii pa lọdun 1986.
Lọdun 1995, Ọgagun Sani Abacha yan an gẹgẹ bi alaga igbimọ to n risi ọrọ yiyi ijọba pada kuro ni ijọba ologun si ijọba alagbada.
Akinyele ni aarẹ ana fun ẹgbe awọn agbẹnusọ lorilẹ-ede Naijiria, NIPR.
Alex Akinyele jade laye loni ọjọ kẹẹdogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019.














