Kogi Election: Dino Melaye náà pariwo pé àwọn apanìyàn ti gbòde ní ìbò ku ọ̀la

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Nibayii ti eto idibo gomina ni ipinlẹ Kogi ku wakati mẹrinlelogun ko bẹrẹ, oniruuru ariwo ni awọn oloselu kan ti n fi sita nipa ihuwasi awọn janduku to gboke.
Obinrin kansoso to jẹ oludije fun ibo gomina ti yoo waye lọjs Satide nipinlẹ Kogi, to tun n soju ẹgbẹ oselu SDP, Natasha Akpoti ti ke gbajare fun araye pe oun n bẹru ẹmi oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwujọ ẹ rọra ṣe ìdájọ́ ẹni tó kọ ọkọ / aya sílẹ̀ nítorí pé kò wùú- Odumosu
- Lai Mohammed: A kò ní bojú wẹ̀yìn lórí àbádòfin ìṣàkóso ẹ̀rọ ayélujára
- Ẹ̀yin ẹ̀ṣọ́, ẹ kò gbọdọ̀ fààyè gba jíjí àpótí ìdìbò ní Kogi àti Bayelsa- Buhari
- Ọlọ́pàá kan jáde láyé, èèyàn méjì fara gbọta lásìkò ìdigunjalè ní Falomo l‘Eko
Idi ni pe wọn lu obinrin yii bi ẹni lu bara ni olu ileesẹ ajọ INEC nibi ipade kan ti alaga apapọ fun ajọ naa pe, ti ọgọọrọ awọn ọlọpa si wa, ti wọn ko si ri janduku kankan to sisẹ naa mu sahamọ.

Oríṣun àwòrán, NAtasha Akpoti
Nigba to n ba BBC sọrọ, Akpoti ni lẹyin ti wọn na oun tan ni wsn tun ti ina bọ ibujoko ẹgbẹ oselu SDP to wa nilu Lọkọja, ti wọn si jo kanlẹ.
"Bi mo se fẹ wọnu ibudo ipade naa, lawsn ọkunrin kan bẹrẹ si tabuku mi, ti wọn si n pe mi ni asẹwo, koda, wọn na mi, ti wọn si ti mi lulẹ ni igba meji niwaju awọn ọlọpa atawọn agbofinro, ti ko si si ẹni to sọ ohunkohun ninu wọn."
"Ni bayii, wọn ti n dunkoko mọ mi pe awọn yoo gbẹmi mi tabi ki wọn ji mi gbe, ti kii si se oni ni awọn eeyan ti n jalaisi nitori oselu lorilẹede Naijiria sugbọn n ko ni jawọ nitori idunkoko wọn."

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Bakan naa, sẹnetọ Dino Melaye ti fi igbe bọnu loju opo Twitter rẹ pe awọn janduku kan ti n dunkoko mọ ẹmi oun ati tawọn mọlẹbi oun.
- Èèyàn méjì farapa nínú ilé tó jóná ní Tejuoso l‘Eko
- Ọlọ́pàá kan jáde láyé, èèyàn méjì fara gbọta lásìkò ìdigunjalè ní Falomo l‘Eko
- Busola Dakolo, lọ san N1m owó gbà má bínú fun Biodun Fatoyinbo - Ileẹjọ
- Ìbò gómìná Bayelsa ku ọjọ́ méjì, Iléejọ́ yẹ àga mọ́ olùdíje APC ńídìí,
- Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu NTA lórí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ìdíje bọ́ọ̀lù
Koda o se afihan ọpọ ohun ti ọta ibọn ba ninu ile aburo rẹ to ni awọn janduku wa ka mọle amọ ori lo ko yọ ti ko ba ibẹ lọ.












