Kogi àti Bayelsa: Irọ́ ni pé wọ́n sèkọlù sí Gómìnà Seyi Makinde - Ọlọ́pàá Kogi

Oríṣun àwòrán, SeyiMakinde/Facebook
Kọmisọnna Ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi, Hakeem Busari ti ni irọ ni pe wọn se ikọlu si Gomina ipinlẹ oyo, Seyi Makinde ni ilu Lokoja.
Busari fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko to n ba ikọ BBC sọrọ lori ẹrọ ipanisọrọ rẹ.
O ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ to n kaakiri naa.
Seyi Makinde ni Alága ẹgbẹ́ òsèlú PDP fún ètò ìdìbò sípò gómìnà tí yóò wáyé ní Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kọkanla, odun 2019.
Awọn agbebọn ya bo Seyi Makinde ní Lokoja!
Awọn agbebọn ti wọn fi oju wọn pamọ ti yabo ile itura ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde wa ni Ilu Lokoja saaju idibo sipo gomina.
Gomina Makinde ni Alaga fun eto idibo sipo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Kogi ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kokanla, ọdun 2019.
Ninu atẹjade ti akowe fun eto iroyin gomina Makinde, Taiwo Adisa sọ wi pe awọn agbẹbọn naa sekọlu si ile itura naa, ti awọn kan si tun gun ọgba naa ni ọsan Ọjọbọ.
Amọ, awọn eleto aabo gomina ati ara agbeegbe naa da ikọlu naa duro, ti gomina si wa ni alaafia.
Ìdí tí ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Kogi fi yàtọ̀!
Ipinlẹ Kogi jẹ eyi ti wọn n pe ni Confluence state nitori pe olu ilu rẹ, Lokoja ni odo Benue ati Niger wa papọ.
Aarin gbungbun Naijiria ni ipinlẹ Kogi wa, iṣẹ agbẹ ni pataki iṣẹ wọn.
Ẹya Ebira, Igala àti Okun ni o pọju nibẹ pẹlu ijọba ibilẹ mọkanlelogun.

Ipinlẹ Bayelsa jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ni guusu Naijiria ti a da silẹ lọdun 1996. Yenogoa ni olu ilu Bayelsa.
Ijaw ni ede ti wọn n sọ julọ nibẹ. Ijọba ibilẹ mẹjọ pere ni wọn ni ni Bayelsa.
Kin lo fa iyatọ ọjọ idibo ipinlẹ Kogi si tawọn to ku?
Ipolongo idibo ọdun 2015 bẹrẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun 2015 ni eyi to pari lọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla ọdun 2015.
Lọjọ Kejilelogun, oṣu kọkanla ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC kede esi idibo nini ijọba ibilẹ mọkanlelogun ni Kogi pẹlu ero pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ ija wa.
Eyi lo mu ki wọn ran awọn ọmọ ogun pupọ lọ sibẹ lẹyin idibo to gbe oludije APC ati PDP jade lọpọlọpọ.
Omọọba Abubakar Audu ti APC ni INEC kede 240, 867 fun nigba ti Captain Wada Idris to jẹ gomina tẹlẹ ni PDP ni 199, 514 nipo keji.
Ogbeni Emmanuel Kucha to jẹ adari eleto idibo lasiko naa fun ipinlẹ Kogi sọ pe idibo naa ko kẹsẹ jari bo ṣe yẹ nitori pe ibo 41, 353 lo wa laarin awọn mejeeji bẹẹ ibo 49, 953 ni wọn wọgile ni eyi to fi jẹ pe ibo ibuso idibo mọkanlelaadọrun un ni wọn ṣi nilo.
Ojọ karun un, oṣu kejila, ọdun 2015 ni wọn ṣatundi ibo naa kaakiri ijọba ibile mejidinlogun kaakiri ipinle Kogi.
Leyin eyi ni ọgbẹni Kucha kede esi pe APC ni 6, 885 ibo ti apapọ ibo APC fi jẹ 247, 752.
Nigba ti PDP ni 5, 363 ninu atundi ibo mọ eyi to wa nilẹ to fi jẹ 204, 877 ibo lapapọ.
Lẹyin iku Abubakar Audu to dupo labẹ APC ni APC fa Yahaya Bello kalẹ ti wọn si kede Yahaya Bello lọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla.
APC ni wọn gbee fun Yahaya Bello tori oun lo ṣe ipo keji Audu laisko idibo abẹlẹ ninu ẹgbẹ APC.
Eyi lo sọ asiko idibo ipinlẹ Kogi di adá tatọ sawọn ipinlẹ guusu ati aarin gbungubn to ku.
- Ta ni Alexander Akinyele, minisita ọrọ iroyin rí?
- Ọlọ́pàá kan jáde láyé, èèyàn méjì fara gbọta lásìkò ìdigunjalè ní Falomo l‘Eko
- "$2,600 àǹtí mi ni mo jí láti lọ sókè òkun àmọ́ àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ mi"
- "Olóṣèlú ní Kogi àti Bayelsa ti ń pín Irẹ̀sì, iyọ̀ lásìkò ìpolongo ìbò, INEC, ẹ mú wọn"
- Wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn ti Alexander Akinyele fi léde kó tó papódà













