World TV Day: Èwo nínú àwọn amóhùnmáwòrán yìí lẹ rántí?

Arúgbó ṣe oge rí, àkísà lògbà rí lọ̀rọ̀ àwọn amóhùnmáwòrán wọ̀nyìí tí ọ̀pọ̀ àgbà ti wá owó kiri láti rà sílé nígbà náà!

tv

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 1: Eyi ni agba ninu awọn amohumaworan ni aye igbaa ni to n gbe ninu kọbọọdu, ti a n fọwọ yii ti yoo maa dun kẹkẹkẹkẹ
TV

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 2: Àwa mẹ́lòó la ránti tẹlifiṣọn ẹlẹsẹ mẹrin yii? Baba mi ra iru rẹ nigba naa, tayọtayọ la fi maa n fi aṣọ ankara ati omi ati adinagbọn nu ẹṣe ati pako ara rẹ!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 3: Ilekile ti a ba ti ri amohunmaworan yii laye igbaa ni, a jẹ pe wọn ṣẹsọ owo nibẹ ni ti wọn ri jájẹ daadaa lagboole nigba naa
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 4: Amohunmaworan yii jẹ eyi ti ẹ ko le ji tàn laarin oru nitori pe yiyi rẹ yoo dun de ibi pe Baba eeyan yoo gbọ ninu iyara ni eyi to ṣeeṣẹ ki eeyan jẹ igba ti si laarin oru pe o ṣe fọwọ kan an
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 5: Awọn kan tun da ajọ ki wọn to ri owo ra amohumaworan oniwo meji ṣaaraṣaara yii lọdun naa lọhun!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 6: Apoti fẹdẹko yii lo maa n jẹ ki idije bọọlu pẹlu awọn oyinbo maa dawati too baa yii si ẹgbe osi ju nigba ti eeyan dudu a jona too baa yii sẹgbẹ otun ju
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 7: Se ẹ ranti atupa oke Telifiṣọn yii? wọn jọ lo igba lasiko kan naa ni. Mo ranti iye ẹgba ti mo jẹ nigba naa pe ẹyin atupa yii fọ lọwọ mi nigba ti mo n fọọ. Aaye atupa naa ni ori iru Telifiṣọn yii nigba naa
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 8: Nigba ti igba kan amohunmaworan yii, iyara awọn 'Big boys' lo ti wọpọ lọdun naa ti wọn fi n mu ọmọge!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 9: Nilu afọju, oloju kan lo n jọba lorọ amohunmaworan yii jẹ lasiko to n lo igba. Ṣe ni gbogbo ọmọde adugbo a maa yọju loju ferese wa wo ere bii Arelu ti wọn yoo maa bóyín gee lati ìta!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 10: Ọmọ taye bi, laye n pọn ni nigba ti telifiṣọn yii jade, lọrọ di oni kọ́lọ̀kọ́lọ̀ lori amohumaworan ti awọn ọdọkunrin n ru pọnunpọnun ati birisope ki wọn le ra sinu iyara kan ti wọn n gbe lọdun naa!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 11: A-wo-dami-ẹnu ni amohunmaworan yii nigba to jade, ile olowo nikan lẹ ti le ri nigba naa
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 12: Nigba ti Telifiṣọn ti a n lẹ̀ mọ ogiri jade, ọlaju ti wọle de, igberaga ti bẹrẹ ninu palọ onikaluku to ba ri jajẹ niwọn ba to de tun le fowo pamọ ra a sile.
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 13: Awọn oṣiṣẹ to wọ inu ajọ lọ ati awọn ti ọwọ wọn to ori ni ẹ maa ba iru telifiṣọn nile wọn lasiko yii nitori o jẹ ọkan lara awọn ti wọn ṣi n ṣakọ lara ogiri ile olowo lasiko yii
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 14: Eyi jẹ ọkan lara awọn to n lo oriṣiriṣi nkan bii ayelujara ati awọn nkan igbalode miran. Telifiṣọn yii maa n jẹ ki aworan inu rẹ tobi ki o dabi pe wọn n duro ba eeyan sọrọ ninun palọ oluwa rẹ ni!
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 15: Aju ara wa lọ, ijakadi kọ ni ọrọ telifiṣọn yii, ko si ohun to n ṣẹlẹ lori ayelujara ti eeyan ko le wo ninu rẹ pẹlu ohùn to ja geere. Ami kan ninu ile awọn ti Olorun gba fun ni telifiṣọn yii jẹ lasiko yii
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 16: Telifiṣọn eyi kọja bẹẹ, aworan inu rẹ maa n jade bii fọto igbalode ni, ohun inu rẹ a ja geere bi ti awoko, eeyan inu rẹ a dabi pe ẹ jọ wa ninu ile, o tun le yipo si ibi ti eeyan ba fẹ ko doju kọ ninu ile nigbakigba.
Telifiṣọn

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Nọ́mbà 17: Eyi jẹ ọkan lara awọn telifiṣọn ti wọn n pe telifiṣọn òmíì ran niṣẹ ninu ile ọlọla. Nṣe lo maa dabi pe ki eeyan kuku wọ inu rẹ lọ ni bi eeyan ba n woo, ọpọ ara to wu olowo ẹ lo le fi da nigba kigba ninu ile.