Kogi 2019: Ohun mẹ́fà tó yẹ ní mímọ̀ nípa Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, @yahaya
Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti kede Gomina Yahaya Bello pe oun lo jawe olubori ninu idibo ipinlẹ Kogi lẹẹkeji.
Oun lo ti n tukọ ipinlẹ naa bọ lati ọdun 2015 titi di asiko yii Yàjóyàjó: Èsì ìdìbò Kogi tó gbé Yahaya Bello wọlé rèé.
Lọjọ Abamẹta to kọja ni eto idibo naa waye kaakiri ijọba ibilẹ mọkanlelogun to wa ni ipinlẹ Kogi.
Wo awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Yahaya Bello:
Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 1975 ni a bi Yahaya Bello ni ilu Okene ni ipinlẹ Kogi.
Yahaya ni abigbẹyin iya rẹ ninu ọmọ mẹfa ti Adédaa fun wọn.
O lọ sile iwe alakọbẹrẹ ti LGEA ni Agassa ni ijọba ibilẹ Okene lọdun 1984.
Yahaya Bello kawe ipele akọkọ nile iwe girama Anyava ni Agassa community secondary school ni Okene.
O gba iwe ẹri ipele girama agba oniwe mẹwaa ni Government Secondary School ni suleja ni ipinlẹ niger lọdun 1994.
Lẹyin eyi ni Yahaya lọ si ile iwe gbogboniṣe ni Zaria ni ipinlẹ Kaduna lati lọkẹkọọ nipa imọ iṣiro owo lọdun 1995.
Yahaya gba oye imọ ijinlẹ ninu iṣiro owo ni ọdun 1999 ni fasiti Ahmadu Bello ni Zaria.
O tun gba oye imọ ijinlẹ ipele keji ti Masters lọdun 2002.
Yahaya Bello di akọṣẹmọṣẹ ti Association of national Accountants of Nigeria lọdun 2004.
O di gomina ipinlẹ Kogi lọdun 2015 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lati rọpo Abubakar Audu to dije dupo naa to si ṣalaisi ki wọn ti kede pe o wọle.
- Yàjóyàjó: Èsì ìdìbò Kogi tó gbé Yahaya Bello wọlé rèé
- Digbi n'ijọba Kogi wa - Yahaya Bello
- Ẹgbẹ́ òṣèlú AA kò gbọdọ̀ kópa nínú ìdìbò gómìnà ní Kogi, Bayelsa - Ilé ẹjọ́
- Ìdìbò gómìnà ku oṣù kan, Buhari ń béèrè N10b fún ìjọba Kogi láti sàn gbèsè rẹ̀
- Ìdí tí mo fi fẹ́ di Gómìnà Kogi - Dino Melaye
- Darandaran tun gbẹmi mẹẹdọgbọn ni Kogi

















