Ikọlu Kogi: Darandaran tun gbẹmi mẹẹdọgbọn

Oku awọn eeyan kan ti ọlọpa ndasọ bo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ojoojumọ ni ẹmi ọpọ eeyan nbọ ninu ikọlu awọn darandaran lorilẹede Naijiria

Ẹnu ko tii sin lara awọn Fulani darandaran lorilẹede Naijiria nitori ikọlu ti wọn nse jakejado orilẹede yii, ti wọn si tun ti sọsẹ mii nipinlẹ Kogi eyi to mu ẹmi eeyan mẹẹdọgbọn lọ.

Nse ni ariwo ẹkun sọ lagbegbe Oganienigwu ati ikende nijọba ibilẹ Dekina to fi mọ Abejukolo nijọba ibilẹ Omala, ti gbogbo wọn wa lẹkun idibo ila oorun ipinlẹ naa.

Ọpọ awọn eeyan si lo ti ndi igba ati agbọn wọn kuro ni abule Obakume, Idirisu ati Oji, ki wọn maa baa se agbako iku ojiji lọwọ awọn darandaran naa.

Iroyin naa ni ko din ni eeyan mẹẹdọgbọn to dero ọrun latipasẹ ikọlu awọn darandaran naa eyi to bẹrẹ lọjọ isẹgun titi wọ ọjọbọ.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Ẹnikan tisẹlẹ naa soju rẹ salaye pe deede aago kan oru lawọn agbebọn yii de pẹlu ibọn AK 47, ti wọn si nde awọn eeyan naa mọlẹ, ki wọn to maa du wọn bii ẹran, ẹnikẹni to ba si gbinyanju lati sa lọ, ni yoo fara gbọgbẹ.

Amọ wọn ti ko awọn agbofinro lọ sawọn agbegbe naa