Dino Melaye, olùdíje sípò kẹẹ̀ta lábẹ́ àsìá PDP tó gba fọ́ọ̀mù ipò Gómìnà Kogi

Oríṣun àwòrán, dinomelaye
Ilumọka oloṣelu ọmọ ipinlẹ Kogi, Senatọ Dino Melaye ti darapọ mọ awọn to n dije dupo Gomina ni ipinlẹ naa.
O gbe igbesẹ yii pẹlu gbigba fọọmu idije lolu ile iṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Abuja.
Dino Melaye to jẹ Sẹnẹto to n ṣoju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi ni oludije kẹta labẹ asia PDP ti yoo gba fọọmu.
Miliọnu mọkanlelogun Nairia ni awọn oludije to fẹ du ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ naa n san lati gba fọọmu ọhun.
Lasiko to n gba fọọmu naa, Dino Melaye ni o da oun loju pe oun yoo jẹ Gomina Kogi ni oṣu Kọkanla ọdun yii lẹyin ti idibo ba waye.

Oríṣun àwòrán, @Dino Melaye
Bakanna lo fọwọ sọya pe oun yoo gba awọn eeyan Kogi kuro lọwọ ijọba amunisin eleyi to ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi Farao tabi Nebukadinesari to n fi iya jẹ awọn ọmọ Isrẹli ninu Bibeli.
Yatọ si Dino Melaye, oludije miiran labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP,Abubakar Suleiman naa gba fọọmu lati dije dupo ninu idibo Gomina ti yoo waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla.









