Kogi Loan: Owó àkànṣe ìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tíjọ́ba Kogi ṣe la fẹ́ dá padà

Oríṣun àwòrán, @A_Oshiomhole
Aarẹ Buhari ti kọ lẹta si ile aṣofin agba lati beere owo to le ni biliọnu mẹwa naira fun ipinlẹ Kogi.
Ninu lẹta kan to kọ si aarẹ ile aṣofin agba Ahmad Lawan, Aarẹ Buhari ni oun fẹ san owo naa fun ijọba ipinlẹ Kogi, ko lee san owo oṣu to jẹ labẹle.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Daura kò tan mọ́ Buhari àmọ́ òun àti ọmọ rẹ̀ ti fẹ́ ba ẹbí mi jẹ́ - Aisha figbe ta
- Ọdún ìbejì sọkutu-wọ̀wọ̀ ní Igboọrà, àṣírí bí wọn ṣe ń bí ìbejì tú
- Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?
Buhari ṣalaye fun awọn aṣofin agba pe gbese owo awọn akanṣe iṣẹ to jẹ ti ijọba apapọ, eleyii ti ijọba ipinlẹ Kogi na owo le lori ni oun fẹ fi owo naa san.

Oríṣun àwòrán, @A_Oshiomhole
Amọṣa, aarẹ ile aṣofin agba ti fa lẹta naa le igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ gbese abẹle ati toke okun fun amojuto to ba yẹ ki o si jiṣẹ pada fun ile naa ni ọsẹ meji.
Ipinlẹ Kogi yoo wọ inu agbami eto idibo gomina ni oṣu kọkanla pẹlu oniruuru iroyin nipa gbese ti wọn ni ijọba jẹ oṣiṣẹ nibẹ.








