Lateef Adedimeji: Toyin Abraham ní ìwọ̀fà lẹnu, Adedimeji wòye pé òbìrí nilé ayé

Toyin Abraham, Lateef Adedimeji ati Odunlade Adekola

Oríṣun àwòrán, Instagram/lateef Adedimeji

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn oṣere ori itage Yoruba, Yollywood gbarada lọsẹ to koja yii. Adedimeji Lateef lo kọkọ woye pe aditu nile aye ti a wa yii.

Wọnyii ni awọn ohun tawọn oṣere Yollywood sọ ati ohun ti wọn ṣe lọsẹ to kọja.

Adedimeji Lateef

Aiye ti wọn n pe ni aye! Gbajugbaja oṣere, Lateef Adedimeji sọrọ loju opo Instagram rẹ, o ni ile aye ko gba ibikan ye oun.

Adedimeji ni oun ti ''ri onile to di ayalegbe ko to dagbare faye,'' bakan naa lo sọ pe oun ti ri akẹkọọ to di ọga ile iwe to ti mkẹkọọ jade nigba tawọn olukọ rẹ si tun wa ni ipo olukọ.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Adedimeji ni ''ko si ẹni to mọ ọla laye ti a wa yii, idi niyii ti aye fi jẹ aditu.''

Adedimeji rọ awọn eeyan lati maa ṣe daadaa nitori aye ko lọ titi.

Toyin Abraham

Oṣere Toyin Abraham naa sọrọ, o ni iwọfa lẹnu, ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fẹnu rẹ sọ.

Toyin sọrọ loju opo Instagram rẹ pe ko si ẹni to lagbara lati dawọn eeyan duro ki wọn maa lee sọrọ rẹ, amọ, ohun to ṣeeṣe ni pe ki onikaluku mọ bi yoo ṣe fesi sọrọ awọn eeyan.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

O fikun ọrọ rẹ pe ko si bi eeyan ṣe le dara to, ko le tẹ araye lọrun.

Toyin Abraham ni ọpọ eeyan ti wọn maa pẹgan fẹ lati maa sọ ohun buburu nipa ọmọlakeji nigba ti wọn dakẹ nigba ohun ti ẹni ti ṣe.

Odunlade Adekola

Gbajugbaja oṣere Odunlade Adekola ni tiẹ sọ ohun to dun n gbọ leti nipa ara rẹ.

Odunlade sọrọ loju opo Instagram rẹ niṣe lara oun n dan an bi egbin.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 3

Odunlade tun sọ fawọn ololufẹ pe ki wọn lọ wo fiimu oun ti akori rẹ n jẹ OGOOLUWA ati ODAJU.

Damola Olatunji

Ilumọọka oṣere Yoruba, Damola Olatunji ati iyawo rẹ, Bukola Awoyemi lọ sori ikanni BBC Yoruba fun ifọrọwerọ.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 4

Lori eto yii Damola ti sọ pe ninu iṣẹ ere tiatia lawọn mejeeji ti pade ko to di pe wọn fẹ ara wọn gẹgẹ bi lọkọlaya.

Ọpọ awọn ololufẹ wọn lo sọrọ ikinni si awọn mejeeji lori eto naa.

Dayo Amusa

Oṣere Dayo Amusa naa ṣawada lju opo Instagram tiẹ ni, koda niṣe lo jiṣoro ara rẹ.

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 5

Dayo sọ fawọn ololufẹ pe ẹnikẹni to ba fẹ oun, ko kan si oun.

Bakan naa ni Dayo Amusa sọ pe awọn eeyan ko oju lọna pọpọṣinṣin ọdun to n bọ diẹdiẹ