Omoyele Sowore: Falana ní ìjọba ti sọ́ di àṣà láti tàpá sófin ilé-ẹjọ́ lórí àwọn tó wà látìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Gbajugbaja agbẹjọro ajafẹtọ ọmọniyan, Femi falana lo sọ pe idi mẹta ọtọtọ ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fawọn ọmọ Naijiria ti ko jẹ ki wọn tii fi Omoyele Sowore silẹ.
Falana ni fifi Sowore sahamọ lẹyin ti ile ẹjọ ti paṣẹ idasilẹ rẹ tabuku ba orilẹede Naijiria.
Ọjọ kẹta oṣu kẹjọ lawọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ mu Sowore niluu Eku ki wọn to gbe e lọ silu Abuja nibi to ti wa lahamọ lati igba naa.
- Wo ẹni tó ń léwájú gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Kogi
- Aàrẹ, igbákejì aàrẹ àti aàrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ̀wé fipò sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- Afunrasí jàǹdùkú 22 lọ́wọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ lórí wàhálà ìdìbò ní Kogi-Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Adedimeji ní àdìtú layé, Toyin Abraham sọ pé kò sẹ́ni tó lè táyé lọ́rùn
- Ìyàwó mi kórira kí Odunlade Adekola máa bú mi nínú eré tíátà - Ijebu
Ọpọ lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ajọ DSS lori bi wọn ṣe kọ lati fun Sowore lominira papaajulọ lẹyin ti ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn fi silẹ.
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ajọ DSS, Ọgbẹni Peter Afunanya sọ pe o wu Sowore fun ra rẹ lati wa latimọle DSS nitori ajọ naa n mojuto o.
Afunanya ni Sowore le wa lẹwọn ṣugbọn o sọ fun ile ẹjọ pe ki wọn jẹ ki oun wa lahamọ DSS.
Amọ Falana ni ijọba apapọ ti sọ di aṣa bayii lati ma pa aṣẹ ile ẹjọ mọ.








