Àwọn orílẹ̀ èdè wo ni Trump tún ń fojúsùn lẹ́yìn Venezuela?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Tom Bennett
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ohun kan tó fẹ́ẹ̀ jọ pé ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump gbájúmọ́ ní sáà rẹ̀ kejì yìí ni àwọn ìpinnu rẹ̀ lórí àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ òkèèrè.
Ó ṣe àmúṣẹ ìdúnkokò rẹ̀ lórí orílẹ̀ èdè Venezuela bó ṣe ṣèkọlù sílé ààrẹ orílẹ̀ èdè náà ní òru, tó sì fi òfin gbé ààrẹ àti ìyàwó rẹ̀.
Nígbà tó ń júwe ìkọlù náà, Trump ní ó jẹ́ àmúṣẹ pé Amẹ́ríkà jẹ ìgàba ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn.
Èyí ni àkójọpọ̀ àwọn ìkìlọ̀ tí Trump ti ṣe fáwọn orílẹ̀ èdè míì láìpẹ́ yìí.
Greenland
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ní ibùdó àwọn ọmọ ogun ní Greenland - Pituffik Space Base - ṣùgbọ́n Trump sọ pé gbogbo erékùsù náà ni òun ń fẹ́.
"A nílò Greenland fún ètò ààbò àpapọ̀ orílẹ̀ èdè wa", ó sọ fún àwọn akọ̀ròyìn. Ó sọ pé àwọn ọkọ̀ ojú omi ńlá ti orílẹ̀ èdè Russia àti china ló kún gbogbo ẹkùn náà.
Erékùsù Greenland, tó jẹ́ lára ẹkùn Denmark, ló wà bíi máìlì ẹgbẹ̀rún méjì sí ìlà oòrùn àríwá Amẹ́ríkà.
Ó ní àwọn ohun àlùmọ́nì tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lórílẹ̀ ayé, èyí tó ṣe pàtàkì láti fi máa ṣe àwọn fóònù, àwọn ọkọ̀ tó ń lo iná ẹ̀lẹ́tíríìkì àtàwọn ohun ìjà táwọn ológun máa ń lò.
Lọ́wọ́ yìí, àwọn ohun àlùmọ́nì tí kò wọ́pọ̀ lórí ilẹ̀ tí China ń pèsè pọ̀ púpọ̀ ju ti Amẹ́ríkà lọ.
Greenland tún wà ní ààyè tó ṣe kókó sí àríwá Atlantic, èyí tó jẹ́ kí wọ́n ní àǹfàní sí omi. Bí àwọn yìnyín bá ṣe ń yọ́ si ni ìrètí wà pé àwọn ọ̀nà tí ọkọ̀ ojú omi yóò le máa gbà tún máa ṣí si.
Olóòtú ìjọba Greenland, Jens Frederik Nielsen fèsì padà fún Trump pé àlá tí kò lè ṣẹ ni èròńgbà láti máa ṣe àkóso erékùsù náà.
Ó sọ pé àwọn ṣetán láti bá Amẹ́ríkà jíròrò, láì sí ìbẹ̀rù tàbí ìfòyàn kankan àmọ́ ó gbọdọ̀ wáyé lọ́nà tó tọ́ àti pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ fún òfin tó de àjọ àgbáyé.
Colombia
Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Trump ṣèkọlù sí Ààrẹ Venezuela ló ṣèkìlọ̀ fún ààrẹ Colombia, Gustavo Petro láti máa wẹ̀yìn rẹ̀ wò.
Colombia, tó pààlà pẹ̀lú Venezuela lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn, ló jẹ́ orílẹ̀ èdè tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ epo rọ̀bì. Bákan náà ló jẹ́ irílẹ̀ èdè tó ń pèsè wúrà, fàdákà, emeralds, platinum àti coal lọ́pọ̀lọpọ̀.
Bákan náà ló tún jẹ́ ibi tí wọ́n ti máa ń ṣòwò egbògi olóró ní ẹkùn náà – pàápàá jùlọ cocaine.
Láti ìgbà tí Amẹ́ríkà ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sáwọn ọkọ̀ ojú omi ní Carribean àti ìlà oòrùn Pacific ní oṣù Kẹsàn-án pé wọ́n ń gbé egbògi olóró ni òun àti ààrẹ orílẹ̀ èdè náà ti ń kọjú oro síra wọn.
Ní oṣù Kẹwàá, ọdún tó kọjá ni Trump fòfin de Petro pé ó ń gba àwọn tó ń ṣòwò egbògi olóró láàyè láti máa gbérí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nínú Air Force One sọ lọ́jọ́ Sunday, Trump sọ pé ẹni tó ń ṣe àárẹ̀ ló ń darí Colombia, tó fẹ́ràn láti máa ṣe egbògi olóró, tó sì ń tà á sí Amẹ́ríkà.
"Kò ní ṣe é fún ìgbà pípẹ́," Trump sọ. Nígbà tí wọ́n bi í léèrè pé ṣé ó máa ṣe ìkọlù sí Colombia, ó fèsì pé ó dùn létí òun.
Nínú ìtàn, Colombia jẹ́ orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ Amẹ́ríkà, tó sì máa ń ràn-án lọ́wọ́ nídìí gbígbógunti egbògi olóró, tó sì máa ń rí ìránlọ́wọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là gbà láti fi kojú àwọn tó ń gbé egbògi olóró.
Iran
Iran ń kojú àwọn olùwọ́de tí wọ́n ń wọ́de tako àwọn ètò ìjọba, tí Trump sì ṣèkìlọ̀ fáwọn aláṣẹ Iran pé òun máa kọlù wọ́n gidi tí àwọn olùwọ́de bá filè jáde láyé si.
"À ń ṣe àgbéyẹ̀wó ibẹ̀ dáadáa. Tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ síní pa àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, mor ò pé Amẹ́ríkà máa ṣe ìkọlù sí wọn gidi," ó sọ fáwọn akọ̀ròyìn lọrí Air Force One.
Iran kò sí lára àwọn orílẹ̀ èdè tó wà lábẹ́ ìlànà "Donroe Doctrine" àmọ́ Trump ti ṣe ìdúnkokò fáwọn aláṣẹ Iran sẹ́yìn láti ṣe ìkọlù sí wọn lẹ́yìn tó ṣe ìkọlù sí àwọn nǹkan ìjà ogun wọn lọ́dún tó kọjá.
Ìkọlù Amẹ́ríkà náà wáyé lẹ́yìn tí Israel bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sáwọn oríkò nǹkan ìjà ogun Iran èyí tó wáyé fún ọjọ́ méjìlá.
Níbi ìpàdé tó wáyé láàárín Trump àti Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu lọ́sẹ̀ tó kọjá, Iran wà lára ohun tí wọ́n sọ̀rọ̀ lé lórí. Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn Amẹ́ríkà sọ pé Netanyahu tún sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe ìkọlù sí Iran lọ́dún 2026.
Mexico
Lára ohun tó gbé Trump dórí ipò ààrẹ Amẹ́ríkà lọ́dún 2016 ni ìpè fún mímọ odì sí ẹnubodè gúúsù pẹ̀lú Mexico.
Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tó padà sí ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ló buwọ́lu òfin láti ṣe àyípadà "Gulf of Mexico" sí "Gulf of America".
Ó ti máa ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn aláṣẹ Mexico kò gbé ìgbésẹ̀ tó láti dènà kíkó egbògi olóró àtàwọn èèyàn wọ Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àìkú, Trump ní láti Amẹ́ríkà ni egbògi olóró ti ń wọ Amẹ́ríkà jùlọ, táwọn yóò sì wá nǹkan ṣe si.
Ààrẹ Mexico Claudia Sheinbaum ti sọ ní gbangba pé àwọn kò ní fi ààyè gba ìkọlù Amẹ́ríkà lórílẹ̀ Mexico.
Cuba
Orílẹ̀ èdè erékùsù, tó wà ní àádọ́ta máìlì sí gúúsù Florida ti wà lábẹ́ ìfofìnde Amẹ́ríkà láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1960. Wọ́n ní ìbáṣepọ̀ tó lóòrìn pẹ̀lú Nicolás Maduro ti Venezuela.
Trump sọ lọ́jọ́ Àìkú pé àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà kò nílò láti ṣe ìkọlù sí Cuba nítorí ó ti ṣetán láti fọ́.
"Mi ò rò pé a nílò láti ṣe ohunkóhun níbẹ̀, ó dàbí pé ó ti fẹ́ wó fúnra rẹ̀.
"Mi ò mọ bí wọ́n ṣe máa ṣe ṣùgbọ́n Cuba kò ní owó kankan mọ́.
"Látara epo Venezuela ni wọ́n ti ń rí owó wọn."
Akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà, Marco Rubio – tí orírun rẹ̀ jẹ́ Cuba – tí máa ń pè fún àyípadà ètò ìṣèjọba ní Cuba tó sì sọ fáwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta pé tí ààrẹ bá ti sọ̀rọ̀, ó yẹ kí wọ́n kà á kún.
"Tí mo bá ń gbé ní Havana, tí mo sì wà ní ìjọba, ominú yóò máa kọmí."












