Ẹnikẹ́ni tí Allwell bá sẹ̀, ẹ dákun, ẹ forí jì í - Rotimi Salami dọ̀bálẹ̀ bẹ àwọn èèyàn

Rotimi Salami lasiko to n bẹbẹ aforiju fun Allwell lọwọ awọn eeyan, nibi eto isinku Oloogbe ni LTV.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Rotimi Salami lasiko to n bẹbẹ aforiju fun Allwell lọwọ awọn eeyan, nibi eto isinku Oloogbe ni LTV.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ẹni to kan lo mọ ni ọrọ iku to pa gbajumọ oṣerebinrin, Allwell Ademola, jẹ, paapaa fun Rotimi Salami, ẹni to jẹ ko-ri-ko-sun fun Allwell nigba aye rẹ.

Ana ode yii ti i ṣe Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni eto isinku Oloogbe Allwell bẹrẹ ninu ọgba Tẹlifiṣan ipinlẹ Eko, nibẹ ni Rotimi Salami si ti ṣe ohun to jọ gbogbo eeyan loju nitori Allwell.

Niṣe ni Rotimi dọbalẹ ni gbagede ti eto ọhun ti waye, pẹlu omije loju, to si ni ki ẹnikẹni ti Oloogbe ba ṣẹ nigba aye rẹ dakun fori ji i, ki wọn ma ṣe ni ikunsinu kankan si oku ọrun.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Aworan Oloogbe Allwell Ademola ti wọn lẹ mọbi eto isinku rẹ ninu ọgba Tẹlifiṣan ipinlẹ Eko

Eto titan abẹla rin kiri lo kọkọ waye lati inu ọgba tẹlifiṣan ipinlẹ Eko, eyi ti ọpọ oṣere kopa ninu rẹ.

Lasiko eto alẹ awọn oṣere ti kaluku ti maa n sọrọ nipa ẹni to ṣalaisi ni Rotimi Salami ṣe ohun ti ẹnikẹni ko fọkan si rara.

Nigba to n fi omije loju ati ibanujẹ ọkan sọrọ, Rotimi ni:

"Njẹ ti a ba ri ẹnikẹni ti Allwell ba ṣẹ, boya o mọ ọn mọ tabi ko mọ ọn mọ, mo n fi asiko yii tọrọ pe ki ẹ ṣe aforijin fun un, ki ẹ si maa gba adura fun un.

"Mo lero pe eyi ni nnkan ti a le ṣe lati le mu iṣọkan wa laarin wa, lati ma le gbagbe Allwell."

Bẹẹ ni oṣere toun ati Allwell jọ maa n kopa ninu fiimu daadaa naa wi, ti awọn eeyan si n rẹ ẹ lẹkun.

Ninu ọrọ tirẹ, osere tiata miran, Abiola Adebayo, sọ nipa Allwell pe Oloogbe naa ya ọpọ fidio nigba to wa laye, ṣugbọn fun igba akọkọ, oun mọ riri awọn fidio naa lẹyin to jade laye.

Adebayo ṣapejuwe Oloogbe gẹgẹ bii ẹgbon ati ọrẹ, ti oun si ri i pe oun ṣe gbogbo ojuṣe oun lasiko to wa laye.

"Lasiko ọjọọbi Allwell ninu oṣu Kẹjọ, mo kan si i pe ki lo fẹ, pe mi o kan fẹ ra ẹbun bi mo ṣe ma n ṣe tẹlẹ, o si ni ka lọ si ile ounjẹ Chinese.

"Mo ni ko pe awọn ọrẹ to ba sun mọ ọn ka jọ lọ. Mi o lailai ro pe Allwell Ademola yoo jade laye loṣu Kejila, ti yoo si jẹ ọjọọbi ikẹyin ni ti oṣu Kẹjọ to ṣe laye.

Ọpọ awọn agba oṣere lo peju sibi eto isinku naa, ti wọm si sọ daadaa nipa Oloogbe Allwell Ademola.

Àwọn òṣere níbi ètò náà

Odunlade Adekola, Rose Odika ati Bolaji Amusan (Mr Latin) nibi eto naa.
Àkọlé àwòrán, Odunlade Adekola, Rose Odika ati Bolaji Amusan (Mr Latin) nibi eto naa pẹlu awọn eeyan mi-in nibi eto naa.

Lara awọn ni oṣere to wa nibi eto naa ni: Saheed Balogun, Iyabo Ojo, Odunlade Adekola, Femi Adebayo, Bolaji Amusan, Yewande Adekoya, Afeez Owo, Kunle Afod, Faithia Williams, Biola Bayo.

Awọn mi-in ni Jaye Kuti, Toyin Alausa, Regina Chukwu, Eniola Ajao, Yemi Solade, Bakare Zainab, Tawa Ajisefinni, Semilore Pweety, Rotimi Salami, Fausat Balogun, Foluke Daramola, Jigan Babaoja ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni wọn yoo gbe Allwell Ademola wọ kaa ilẹ lọ ni itẹ oku Atan, Yaba nipinlẹ Eko.

BBC News Yoruba yoo maa mu eto naa wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Òní ni ètò ìsìnkú Allwell Ademola yóò bẹ̀rẹ̀

Oloogbe Allwell Ademola

Oríṣun àwòrán, Allwell Ademola/Facebook

Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni eto bi wọn yoo ṣe sinku gbajumọ obinrin onitiata nni, Ọmọbabinrin Allwell Ademola, yoo bẹrẹ niluu Eko.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni a ti fi to yin leti pe isin orin onigbagbọ ni yoo kọkọ waye loni 'Ọjọbọ, bẹrẹ lati aago mẹrin irọlẹ titi di aago mẹfa.

Eto ti yoo si kan lẹyin rẹ ni titan abẹla.(Candlelight procession.)

Gẹgẹ bi ikede isinku Oloogbe Allwell ṣe tẹsiwaju, aago mẹfa irọlẹ ni titan abẹla naa yoo ti bẹrẹ, wọn yoo si ṣe e fun wakati kan.

Lati inu ọgba Tẹlifiṣan ilu Eko (LTV) ni titan abẹla yoo ti bẹrẹ, wọn yoo rin de ikorita Oregun, wọn yoo si pari rẹ pada si LTV.

Kete lẹyin ti wọn ba dari nibi titan abẹla ni aṣalẹ awọn oṣere (Artists night) yoo bẹrẹ, nibi ti wọn yoo ti maa sọrọ nipa Oloogbe.

Bi oṣere tiata, Rotimi Salami to jẹ ko-ri-ko-sun fun Oloogbe Allwell ṣe kede, aṣọ ti a mọ si T-shirt, ti wọn ya Allwell si pẹlu orukọ rẹ, yoo wa fun awọn olubanikẹdun lati wọ l'Ọjọbọ naa.

Ìsìnkú gan-an yóò wáyé lọ́la ọjọ́ Ẹti, ọjọ kẹsan-an oṣu Kin-in-ni ọdun 2026

Gẹgẹ bi atẹjade to kede eto isinku Oloogbe Allwell ṣe wi, ọla ode yii ti i ṣe ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni wọn yoo sin oṣere tiata naa.

Itẹ oku Atan, to wa ni Yaba, niluu Eko ni wọn yoo sinku si. Aago mẹwaa aarọ ni eto isinku naa yoo si waye.

Awọn abanikẹdun le wọ aṣọ funfun bii T. shirt le ori aṣọ ti a mọ si Jeans fun isinku, bi wọn ṣe kede.

Bi wọn ba ti sinku tan, ki kaluku gba ile wọn lọ ni atẹjade isinku naa wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọkan Allwell Ademola ni wọn lo deede daṣẹ silẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025, to si ṣe bẹẹ dagbere faye lẹni ọdun mọkandinlaadọta (49).

Ta ni Oloogbe Allwell Ademola?

Oloogbe Allwell Ademola

Oríṣun àwòrán, Allwell Ademola/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ ọdun 1976 ni wọn bi Allwell Ademola siluu Eko, sinu idile Ademola ti i ṣe idile ọba Alake Ademola tiluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun.

Ọmọ ọba ni Allwell latari eyi, bẹẹ si ni baba to bi baba rẹ ni Adajọ agba akọkọ lorilẹede Naijiria, iyẹn Oloogbe Adetokunbo Ademola.

Ọdun 1986 lo kọkọ bẹrẹ iṣẹ tiata gẹgẹ bi oṣeremọde lori eto "Animal Games" ti ọpọ n gbadun lori ẹrọ tẹlifiṣan NTA lọdun naa lọhun-un

Oloogbe naa tun maa n kọ orin, oun lo da ẹgbẹ akọrin "Allwell and Company," silẹ lọdun 2002, ti ẹgbẹ naa si gbe awo orin kan jade lọdun 2006

Ademola ti gba oniruru ami ẹyẹ, lara rẹ ni ipa to ko ninu ere "Hakunde" lọdun 2016

Lara awọn fiimu ti oun funra ti gbe jade ni "You or I" (2013), "Omo Emi" (2017), ati "Ile Wa" (2018)

Ademola kekọọ nipa ere ṣiṣẹ, iyẹn, Dramatic Arts ni Fasiti Obafemi Awolowo to wa niluu Ile Ife, ipinlẹ Osun.

Yatọ si iṣẹ tiata, Oloogbe naa tun jẹ oloju aanu to maa n bu ẹnu atẹ lu awọn nnkan ti ko yẹ lawujọ ni Naijiria

Ipa ti Allwell ti ni lara iṣẹ tiata ni Naijiria ko kere rara, awọn ohun to ti ṣẹ sẹyin ko si ni ṣe e fọwọ rọ sẹyin

Ọrọ to gbe jade kẹyin ni fidio to fi soju opo Instagram rẹ, nibi to ti n kọ orin pe oun yoo ri opin ọdun 2025 yii lai mọ pe ọjọ keji rẹ loun yoo dagbere faye.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025 ni Allwell jade laye, lẹyin ti ọkan rẹ deede daṣẹ silẹ.

Wọn sare gbe e lọ sile iwosan bi wahala naa ṣe de, ṣugbọn Ẹlẹmii gba a lọjọ Sadide naa ti I ṣe ọjọ kẹta ọdun Keresimesi to kọja.