Ìdí tí iléeṣẹ́ Nestle ṣe fẹ́ dáwọn oúnjẹ ọmọdé tó tà sita padà àti bí o ṣe lè mọ oúnjẹ náà

Aworan iya to n fun ọmọ ni ounjẹ lati inu ife ijẹun ọmọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ Nestle ti da awọn ounjẹ ọmọde kan ti wọn ta sita pada lori wi pe majele to le ṣakoba fun ara wa ninu awọn ounjẹ naa.

Gbajugbaja ileeṣẹ ounjẹ ati ọti naa ṣalaye pe irufẹ ounjẹ SMA ọmọde naa lewu lati fun awọn ọmọde.

Nestle ni kaakiri agbaye lawọn ta ounjẹ naa ti kẹmika cereulide wa ninu rẹ si, eyi to le jẹ ki ọmọde maa bi ti o ba jẹ ẹ.

Ileeṣẹ naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe ko tii si akọsilẹ ẹnikan kan to ṣaisan lẹyin to jẹ ounjẹ naa tan, wọn ni awọn pinnu lati ko ounjẹ naa kuro lori igba lati daabo bawọn onibaara ni.

''Igbayegbadun ati wiwa lai lewu awọn ọmọde lo jẹ wa logun.

A tọrọ aforijin lọwọ gbogbo obi, alagbatọ atawọn onibaara wa ti igbesẹ wa yii ba fa inira fun,'' Nestle lo sọ bẹẹ.

Ileeṣẹ naa sọ fun BBC pe kaakiri agbaye lawọn ti n da ounjẹ naa pada.

Nestle ta irufẹ ounjẹ yii sawọn orilẹede bii France, Germany, Austria, Denmark, Italy ati Sweden nilẹ Yuroopu.

Ileeṣẹ naa ni ko sewu pẹlu awọn ounjẹ mii ti Nestle ṣe yatọ si eyi tawọn fẹ da pada.

Nestle ṣeleri lati da owo awọn onibaara to ra ọja naa pada

Nestle ti wa ṣeleri lati da owo awọn onibaara to ra ọja naa pada.

Wọn ni ẹnikan to ko eroja tawọn maa n lo wa lo fa nnkan to ṣẹlẹ yii.

Eeyan le ri orukọ ounjẹ ti Nestle fẹ da pada yii lori ikanni Nestle ni UK tabi lori ikanni food.gov.uk.

Cereulide jẹ kẹmika kan ti kokoro Bacillus cereus maa n jade lati ara rẹ eyi to le fa majele ninu ounjẹ.

Kẹmika yii le jẹ ki eeyan maa bi tabi ki inu maa run eniyan.

Ajọ FSA to n ri si ọrọ ounjẹ ti sọ pe kokoro naa le ma ku ti eeyan ba se ounjẹ naa lori ina.

Ọga agba ajọ FSA, Jane Rawling, rọ awọn obi, alagbatọ ati gbogbo eeyan to ti ra ounjẹ naa wi pe ki wọn ma ṣe fawọn ọmọ wọn.

O tun rọ awọn to ba ti fọmọ wọn lounjẹ naa wi pe ki wọn beere imọran lọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ oṣiṣẹ eleto ilera.