Ìdìtẹ̀gbàjọba ní Burkina Faso forí sánpọ́n, Traoré móríbọ́ lọ́wọ́ ikú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ ède Burkina Faso ti kéde pé ìgbìyànjú láti gba ìjọba mọ́ ọ̀gá ológun Ibrahim Traoré ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ti forí sánpọ́n.
Mínísítà fún ètò ààbò Burkina Faso, Mahamadou Sana nínú ìkéde tó ṣe sọ pé ológun kan Paul Henri Damiba ló gbìyànjú ìdìtẹ̀gbàjọba tí kò kẹ́sẹ járí náà.
Ó ní lásìkò tí ìgbìyànjú àwọn ológun náà ti dé ipele tó kẹ́yìn ni wọ́n ba èròńgbà náà jẹ́.
"Wọ́n gbèrò láti ṣekúpa Traoré, kí wọ́n wá ṣèkọlù sáwọn iléeṣẹ́ ìjọba tó ṣe kókó, tó fi mọ́ àwọn alágbádá."
Sana fẹ̀sùn kàn pé orílẹ̀ èdè Ivory Coast wà lára àwọn tó ń ṣe àtìlẹyìn fún Damiba láti gba ìjọba mọ́ Traoré lọ́wọ́.
Ọ̀gágun Damiba àti orílẹ̀ èdè Ivory Coast kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí àwọn ẹ̀sùn náà.
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìpèníjà tó ń kojú àti pé ó jẹ́ ológun, Traoré, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ṣì ń rí àtìlẹyìn àwọn aráàlú rẹ̀, tọ fi mọ́ káàkkiri ẹkùn Africa pàápàá bó ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òyìnbó amúnisìn.
Gẹ́gẹ́ bí mínísítà fétò ààbò náà ṣe sọ, wọ́n ṣàwárí fídíò kan tó ṣàfihàn báwọn ológun náà ṣe ń gbèrò láti gbàjọba mọ́ Traoré lọ́wọ́.
Ó fẹ̀sùn kàn pé alẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kìíní ọdún, 2026 ni wọ́n ṣe ìpàdé náà níbi tí wọ́n ti ń jíròrò nípa ìlànà tí wọ́n máa lò láti fi pa olórí orílẹ̀ èdè náà.
Ó ní wọ́n jíròrò pé bóyá kí àwọn yìnbọn pa á tàbí kí wọ́n sọ àdó olóró sí ilé rẹ̀.
Sana sọ pé lẹ́yìn náà ni wọ́n ní àwọn máa ṣèkọlù sáwọn olórí ológun míì àtàwọn alágbádá tí wọ́n lórúkọ.
Ó tún fẹ̀sùn kàn Damiba ti rí àtìlẹyìn àwọn ológun àti alágbádá kan, tó sì tún ti rí ọ̀pọ̀ owó gbà láti Ivory Coast. Ó ní ó gbèrò láti ṣèkọlù sí ohun ìjà olóró dúróònù àwọn ológun kí àtìlẹyìn tó dé láti ilẹ̀ òkèèrè.
"À ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́, a sì ti mú ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn èyí ta máa fi jófin láìpẹ́," mínísítà náà sọ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Sana tẹmpẹlẹmọ pé àwọn ti ń kojú ìdìtẹ̀gbàjọba náà, tí wọ́n sì rọ àwọn aráàlú láti má jẹ̀ ẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣì wọ́n lọ́kàn.
A kò tíì le sọ iye èèyàn tí wọ́n ti fi póró òfin gbé báyìí.
Àwọn lámẹ̀yítọ́ tó fi mọ́ abẹ́lé àti ilẹ̀ òkèèrè ti fẹ̀sùn kan Traoré pé ó ń ṣèjọba bíi apàṣẹ wà á, tó sì ń lo ìṣèjọba rẹ̀ láti fi pa àwọn èèyàn lẹ́nu mọ́ tó fi mọ́ fífi òfin gbé àwọn ológun lọ́nà àìtọ́ àtàwọn akọ̀ròyìn.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí Traoré ń nàka sí Ivory Coast pé ó ń dá sí ètò orílẹ̀ èdè òun.
Àwọn ìfaǹfà tó ń wáyé ti ń mú àlékún bá inú fu àyà fu ní ẹkùn náà.
Ọ̀gágun Damiba ti ṣe olórí ológun Burkina Faso láàárín oṣù Kìíní sí oṣù Kẹsàn-án 2022 lẹ́yìn tí wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ ìjọba alágbádá.
Lẹ́yìn tí Traoré gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀ ló sálọ sí orílẹ̀ èdè Togo, tó sì sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé lórí ayélujára pé òun gbàdúrà kí ẹni tó bá ṣèjọba lẹ́yìn òun ní oríire.














