Agbébọn ṣàfihàn fídíò ọ̀gọ̀rọ̀ èèyàn tí wọ́n jí gbé ní Kwara, wọ́n ní 176 làwọn jí gbé, kìí ṣe 32

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Kayeefi lọrọ naa jẹ lọjọ Abamẹta lẹyin ti awọn agbesunmọmi gbe fọnran kan sori ayelelujara to safihan ọgọrọ awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn ji gbe ni Kwara.
Ninu fọnran naa ni eeyan kan ti n sọrọ lede Hausa, to si n bi awọn obinrin naa lere ibi ti awọn ti ji wọn gbe.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹta osu Keji, ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn ṣakọlu si ilu Woro ni ijọba ibilẹ Kaiama ni ipinlẹ Kwara ti wọn si pa ọgọọrọ eeyan, wọn si tun gbe aimọye awọn obinrin ati awọn ọmọde gbe lọ.
Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba kede iye eeyan ti wọn ji gbe, to si sọ pe iṣẹ ti n lọ lati doola wọn eeyan naa.
Amọ ṣa, awọn agbesunmọmi naa tig be fidio jadem ninu eyii ti wọn ti sọ pe iye eeyan ti awọn ji gbe lọ pọ ju iye eeyan ti ijọba kede faraye.
Ninu fidio ọhun ni wọn ti sọ ede Hausa.
Ohun tí wọ́n ń sọ lédè Hausa
Ni ibẹrẹ fọnran naa lati ri ọpọlọpọ awọn obinrin ati awọn ọmọde loju iran, ohun kan si wọle lede Hausa bayii pe:
"Wọn yii ni awọn ti a ji gbe ni Kwara" lẹyin naa lo wa n bi awọn obinrin ti wọn wa niwaju leere lọkọọkan pe, "nibo lati ko yin?" Wọn si daa lohun pe, Woro.
Ohun naa tun beere pe, "ijọba ibilẹ wo, ipinlẹ wo? Wọn tun fesi pe "ilu Woro ni ipinlẹ Kwara ni."
Lẹyin naa lo tun pe obinrin kan niwaju to wọ aṣọ pupa pe, "iwọ alasọ pupa yii, nibo lati gbe ọ?" ohun naa si tun fesi pe "Woro ni ijọba ibilẹ Kaiama ni ipinlẹ Kwara ni."
Lẹyin ibeere ati idahun yii ni ohun naa sọ pe, "ijọba n pa irọ, eeyan 176 la gbe ni Woro, kiiṣe 32 tabi 20 ti ijọba sọ fun awọn eniyan".
Òótọ́ ni ò, àwọn èèyàn wa ni wọ́n wà nínu fọ́nrán náà - Aráàlú
BBC Yoruba kan si eeyan kan ni ilu Woro ti iṣẹlẹ naa ti waye lati mọ boya otitọ tabi ayederu ni fọnran naa.
Arakunrin Danjuma Mahmud to ba wa sọrọ lori agọ sọ pe, otitọ ni fidio naa ati pe awọn da awọn kọọkan mọ ninu fidio ọhun.
Mahmud sọ pe "Koda, awọn obinrin ilu gan-an sọ pe iyawo ọba ilu wa lara awọn obinrin ti wọn wa ni iwaju."
"Àwọn agbébọn nìkan ni wọ́n lè mọ iye àwọn tí wọ́n jí gbé, ìjọba Kwara ò lè sọ"
Lori ọrọ ti wọn sọ lede Hausa wi pe ijọba Kwara pa irọ fun awọn eniyan pẹlu iye eeyan ti awọn ji gbe lọ ni ilu naa, Danjuma Mahmud sọ pe, ko si ẹni to mọ iye eeyan ti wọn ji ko lọ ayafi awọn ti wọn ji wọn ko.
"Ko si eeyan kan to mọ iye awọn ti wọn ji, ijọba o le mọ iye wọn, koda awọn araalu gan-an o lee sọ.
"Idi ni pe, ọpọlọpọ awọn ti a o ri, ti a si ro pe wọn ti ji wọn gbe lọ la pada ri.
"Ati pe, yatọ si awọn ti wọn ko lọ ninu ilu, bi wọn ṣe n lọ, wọn pade awọn eeyan ninu igbo, wọn si ko wọn lọ, awọn mii ti wọn tun ba ninu oko, wọn tun ko wọn pẹlu awọn ti wọn jigbe pẹlu.
"Fun idi eyi, ko sẹni to mọ iye araalu ti wọn ji ko, awọn ti wọn ji wọn ko ti wọn ni 176 nikan lo le mọ, ti wọn si lee sọ"
A ò fìgbà kan sọ iye èèyàn tí wọ́n jí gbé lọ ní pàtó - Ìjọba Kwara fèsì
Ẹwẹ, ijọba Kwara ti fesi si fọnran naa wi pe ko si igba kan ti awọn sọ pe iye eeyan bayii ni wọn ji gbe lọ ni pato, pe ohun to jẹ awọn logun ni bi awọn ti wọn ji gbe yoo se gba ominira.
Ijọba sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna to n ri si eto iroyin, Bolanle Olukoju, fi lede lẹyin fidio naa.
Olukoju sọ pe, orisirisi iye ni o jade, ijọba o si figba kan di iye kan mu.
O ni, fidio naa jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ, ijọba si ti bẹrẹ isẹ takuntakun pẹlu awọn agbofinro lati da awọn ti wọn wa nibẹ mọ ati lati doola wọn.
O ṣee lalaye pe, ijọba ti kan si awọn olori ilu Woro lati wo fọran naa fun idanimọ, ṣgbọn awọn eeyan diẹ ni wọn si daamọ nibẹ gẹgẹ bii araalu Woro.
O ni ọpọlọpọ awọn ti wọn n wa tẹlẹ ni wọn ti pada sile, bẹẹ si ni awọn mii ti ko lọ si awọn ilu ti wọn wa ni agbegbe.
O fi kun-un pe, ọkan ijọba wa pẹlu awọn ti wọn wa lakata ajinigbe ati awọn ẹbi wọn, pe ijọba si n ṣe ohun to tọ lati ri wi pe, wọn gba itusilẹ wọn ki wọn si pada wale.



























