Àkójọpọ̀ èsì ìdìbò alága àti kánsẹ́lọ̀ tó wáyé nílùú Abuja lópin ọ̀sẹ̀

Oríṣun àwòrán, Chukwunaeme Obiejesi/BBC
Ajọ eleto idibo INEC ti kede esi idibo alaga ati kansẹlọ to waye lọjọ Abamẹta ọjọ kọkanlelogun oṣu Keji yii niluu Abuja.
Awọn esi eto idibo naa to waye ni ijọba ibilẹ mẹfa to wa l'Abuja lawọn eeyan ti n ri wo lori itakun ayelujara IReV lẹyin ti eto idibo naa waye tan.
Akiyesi ti a ṣe ni pe ọpọ oludibo ni ko jade lati kopa ninu eto idibo naa.
Eyi ni eto idibo akọkọ ti ajọ INEC yoo ṣagbatẹru rẹ lẹyin atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti ile igbimọ aṣofin ṣe eyi to fa awuyewuye.
Ọjọru ọjọ kejidinlogun ọsẹ to kọja yii naa ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu ofin naa lẹyin ti ile aṣofin mejeeji ṣiṣẹ lori rẹ tan.
Eto idibo yii tun ni ẹlẹẹkeji ti alaga ajọ INEC tuntun, Ọjọgbọn Joash Amupitan, yoo ṣagbatẹru rẹ lẹyin to de ipo lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2025 to kója.
Eto idibo to kọkọ ṣe ni ibo gomina ipinlẹ Anambra to waye loṣu Kokanla ọdun to kọja.
Wọnyi ni awọn esi idibo alaga ati kansẹlọ to waye niluu Abuja:
Ijọba ibilẹ Gwagwalada
Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Mohammed Kasim, lo wọle ibo alaga ijọba ibilẹ Gwagwalada.
Ọga agba INEC, Philip Akpen, lo kede esi ibo naa lọjọ Aiku ọjọ kejilelogun oṣu Keji yii.
Ọga ajọ INEC ni Kasim ri ibo 22,165, nigba ti alatako rẹ, Yahaya Shehu, oludije ẹgbẹ oṣelu APC ri ibo17,788.
Ajọ INEC sọ pe eeyan 207,577 lo forukọ silẹ fun eto idibo naa ni ijọba ibilẹ Gwagwalada, amọ,46,294 pere lo lọ si ibudo idibo lati forukọ silẹ lọjọ idibo.
Esi ibo
A: 151
AA: 116
ADC: 1,366
ADP: 128
APC: 17,788
APGA: 1,687
APM: 24
NNPP: 175
PDP: 22,165
SDP: 432
YPP: 158
Iye ibo ti wọn ka: 43,960
Ibo ti wọn o ka: 1,521
Ijọba ibilẹ Abuja Municipal Area
Ajọ INEC kede Christopher Maikalangu, oludije All Progressives Congress gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ibo alaga ijọba ibilẹ Abuja Municipal Council.
Andrew Abue ni o ko esi ibo ijọba ibilẹ naa jọ
Esi ibo
A: 403
AA: 108
ADC: 12,109
ADP: 588
APC: 40,295
APP: 32
APGA: 1,111
APM: 122
BP: 43 votes
NNPP: 1,694
NRM: 73
PDP: 3,398
PRP: 90
SDP: 2,185
YPP: 421
ZLP: 189
Ijọba ibilẹ Bwari
Joshua Ishaku oludije ẹgbẹ All Progressives Congress ni ajọ INEC kede wi pe o wole ibo alaga ijọba ibilẹ Bwari.
Ishaku ri ibo18,466 eyi to fi la awọn oludije ẹgbẹ oselu yooku mọlẹ ninu eto idibo naa.
Ọga agba INEC Ọjọgbọn Mohammed Nurudeen lo kede esi ibo naa lọjọ Aiku.
Ẹsi ibo
APC: 18,466
ADC: 4,254
ZLP: 3,515
Ijọba ibilẹ Kwali
Daniel Nuhu, oludije All Progressives Congress lo wọle ibo alaga ijọba ibilẹ Kwali.
Ajọ INEC sọ pe ibo 16,656 ni Nuhu ri to fi la awọn alatako rẹ mọlẹ.
Haruna Pai, oludije ẹgbẹ Peoples Democratic Party, to ṣe ipo keji ri ibo 8,467.
Esi ibo
APC: 16,656
PDP: 8,467
Ijọba ibilẹ Abaji
Umar Abdullahi ti i ṣe oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lo wọle ibo alaga ijọba ibilẹ Abaji.
INEC kede wi pe ibo 15,535 ni Abdullahi ri eyi to gbe e wọle ibo naa.
Esi ibo
APC: 15,535
PDP: 4,547
ADC: 37
NNPP: 53
A o maa mu iroyin lori esi ibo yooku wa fun yin to ba ti tẹ wa lọwọ.



























