Nígbà tí ìbọn kò wọlé sí Kábíyèsí lára ni àwọn agbébọn fọ́ nǹkan mọ́ Òba Agamo lórí - Mọ̀lẹ́bí
NI ọsẹ to kọja ni a gbọ pe awọn agbebọn ṣekupa ori ade Ilu Agamo nipinlẹ Ondo, Oba Kehinde Falodun ni aafin rẹ.
Iṣẹlẹ yii lo mu ki BBC News Yoruba gbera si ilu Agamo lati mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
Ọkan lara awọn mọlẹbi to ba wa sọrọ ni iṣẹlẹ naa waye ni irọlẹ lasiko ti Kabiyesi n ba awọn eeyan kan sọrọ ni agbala aafin.
"Awọn kan lo wa lojiji, wọn dẹ wa pẹlu ibọn, awọn mẹwaa.
"Kabiyesi joko si bi, ni nnkan bi ago meje pẹlu awọn kan, wọn tiẹ sọ pe bayii, wọn kan bẹrẹ si ni ma yin Oba nikan.
"Koda wọn yin ibon yẹn ju ọgọrun igba lọ, kete ti wọn ti pe ọta o wọle, igba naa ni wọn wọ Kabiyesi si odi keji, ti wọn si la igi mọ lori."
Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Abdebowale Lawal naa ṣe abẹwo si ilu Agamo, to si rọ awọn araalu pe ki wọn fi ọkan wọn balẹ nitori owo yoo tẹ awọn agbebọn naa ni aipẹ.




