Kenya fòfin de fífi owó ṣe òdòdó

Owó Kenya tí wọ́n lọ́ papọ̀ láti fi ṣe òdòdó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ìfowópamọ́ àgbà ní orílẹ̀ èdè Kenya, Cntral Bank of Kenya ti ṣèkìlọ̀ fáwọn aráàlú orílẹ̀ èdè náà láti dènà fífi owó ṣe òdòdó èyí tí àṣà rẹ̀ ti ń gbilẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà báyìí.

Ní àsìkò tí àyájọ́ olólùfẹ́ bá ń bọ̀ lọ́nà báyìí ni àṣà fífi owó ṣe bíi òdòdó máa ń gbilẹ̀ jùlọ, táwọn gbajúmọ̀ àtàwọn ìlúmọ̀ọ́ká sì sábà máa ń ṣe.

Àwọn gbajúmọ̀ láàárín ìlú máa ń ṣe fídíò ara wọn bí wọ́n ṣe gbà ẹ̀bùn owó náà tàbí bí wọ́n ṣe fún èèyàn.

Láti fi owó ṣe òdòdó, wọ́n máa ká owó, tí wọ́n sì máa to àwọn owó náà papọ̀ dáadáa láti lè jẹ́ kó dàbí òdòdó.

Àmọ́ ilé ìfowópamọ́ àgbà ní orílẹ̀ èdè Kenya ní fífi owó ṣe òdòdó ń tàbùkù owó orílẹ̀ èdè náà nítori ó ń kó àléébù bá àwọn owó náà.

Ilé ìfowópamọ́ náà ní ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀ ṣeéṣe kó kojú ṣíṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méje.

Nínú àtẹ̀jáde tí ilé ]ifowópamọ́ náà fi síta sọ pé ìgbésẹ̀ fífi owó ṣe òdòdó máa ń gba kí wọ́n ká owó, fi píìnì mu, tàbí lẹ̀ ẹ́ papọ̀ èyí tó máa ń ní ipa lórí àwọn owó bẹ́ẹ̀ pàápàá tí wọ́n bá kó wọn sínú ẹ̀rọ tó ń pọ owọ jáde, ATM.

Wọ́n fi kun pé ó tún máa ń ṣokùnfà káwọn èèyàn máa kọ owó nítorí pé wọ́n ti bàjẹ́, tó sì máa ń jẹ́ ìnáwó míì fún ilé ìfowópamọ́ náà láti pààrọ̀ wọn pẹ̀lú tuntun.

Ẹ̀wẹ̀, ilé ìfowópamọ́ náà ní àwọn kò lòdì sí káwọn èèyàn máa fún ara wọn ní ẹ̀bùn owó ṣùgbọ́n kí wọ́n wá ọ̀nà míì láti ṣe bẹ́ẹ̀ láì ba owó orílẹ̀ èdè náà jẹ́.

Ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ tí wọ́n ti máa ń gbin òdòdó lọ́pọ̀ yanturu ni Kenya jẹ́.

Ìkéde ilé ìfowópamọ́ àgbà yìí jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn faramọ́, tí wọ́n sì ń sọ pé yóò mú ìgbéga fífún àwọn èèyàn ní òdòdó gangan lásìkò àyájọ́ olólùfẹ́ tó ń bọ̀ lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kejì.

Bákan náà ló tún ń fa onírúurú àríwísí lórí ayélujára.

Alinur Mohamed kọ sójú òpó X rẹ̀ pé "ìkéde ilé ìfowópamọ́ àgbà náà yóò kó àwọn ọkùnrin yọ lásìkò àyájọ́ olólùfẹ́ tó ń bọ̀ lọ́nà. À ń padà sí ìpìlẹ̀, òdòdó gangan ni."

Ẹlòmíràn sọ pé ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ aráàlú faramọ́ pàápàá fáwọn tó rí fífi owó ṣe òdòdó bíi ohun tó wọ́n púpọ̀.