Kí ló dé tíjọba Tinubu ní káwọn ìpínlẹ̀ máa pín owó ìrànwọ́ orí iná mọ̀nàmọ́ná san pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀? Àlàyé rèé

Aarẹ Bola Tinubu wọ aṣọ buba olomi buluu atawọn gomina ipinlẹ Yoruba mẹrin tawọn naa wọ ọkan o jọkan aṣọ buba

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/Babajide Sanwo-Olu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti kede wi pe oun nikan kọ ni yoo maa sanwo iranwọ ori ina mọnamọna mọ bayii, ijọba ti ni awọn ipinlẹ naa yoo san ninu owo naa bayii.

Ọga agba ọfiisi to n ri si eto iṣuna ni Naijiria, Tanimu Yakubu, lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to ṣepade pẹlu awọn ileeṣẹ ati oriṣiiriṣii ẹka ijọba niluu Abuja lanaa ọjọ Aje ọjọ keji oṣu Keji ọdun 2026 yii.

Ọgbẹni Yakubu sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe ki ẹka ijọba mẹtẹẹta maa pin owo iranwọ ori ina mọnamọna san.

O ni aarẹ sọ pe bi ijọba apapọ nikan ṣe n da sanwo naa lo n jẹ ki oriṣiiriṣii iṣoro to n koju ẹka ipese ina ọba maa pọ si.

''Ti a ba n fẹ ina ọba to duro deedee, a ni lati sanwo fun un ni.

Ti owo ina ti araalu n san ko ba gara, o tumọ si pe ijọba n san owo iranwọ lori ina mọnamọna ni.

Lọdun 2026 yii, ijọba apapọ ko ni maa da owo iranwọ ori ina mọnamọna san mọ.

Ijọba ipinlẹ atawọn ijọba ibilẹ naa yoo jọ maa pin ninu bowo naa san bayii,'' Yakubu ṣalaye.

Ọga agba ọfiisi eto iṣuna ni Naijiria ṣalaye pe ijọba apapọ ko gbe igbesẹ yii lati fiya jẹ ẹnikẹni, bi ko ṣe lati jọ ṣiṣẹ pọ ki ẹka ipese ina ọba le fẹsẹ rinlẹ ni Naijiria.

Awọn gomina fesi lori ikede ijọba apapọ lori sisan owo iranwọ ori ina ọba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbimọ ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, NGF, ti fesi si ikede ijọba pe awọn ipinlẹ naa yoo maa san ninu owo iranwọ ori ina mọnamọna lati ọdun 2026 yii lọ.

Adari eto eto iroyin ohun ọrọ to n lọ, Yunusa Abdullahi, ti sọ pe awọn gomina ti bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo ikede ti ijọba apapọ ṣe ọhun lori pinpin owo iranwọ ori ina san.

Abdullahi sọ pe awọn gomina ko ni tii sọrọ bayii, o ni to ba to asiko lawọn yoo sọrọ lori ikede ijọba apapọ.

Bakan naa, ajọ SERCs to n ṣakoso ọrọ ina mọnamọna nipinlẹ Eko, Imo, Enugu, Ekiti, Oyo, Ondo, Edo, Niger, ati Anambra naa ṣe ipade pajawiri lori ayelujara lati jiroro lori ikede ijọba apapọ lori pinpin owo ina san.

Ajọ naa sọ pe lẹyin tawọn ba ṣe agbeyẹwo ikede naa tan lawọn yoo sọ igbesẹ to kan fawọn lati gbe.

Oṣiṣẹ kan to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ naa sọ pe awọn ni lati mọ kulẹ kulẹ nnkan to wa ninu ikede ijọba kawọn to le fesi le e.

Oṣiṣẹ naa sọ pe ijọba apapọ ti gbawọn igbesẹ kan laipẹ nipa siṣọ ileeṣẹ to n ri si ipese ina ọna di ti aladaani.

Amọ, o ni awọn ni lati ṣe ayẹwo igbesẹ ijọba apapọ yii finifini lati le mọ iru igbesẹ tawọn yoo gbe lori ọrọ naa.