Wo orúkọ àwọn ọmọ Nàìjíríà 79 tí Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà sílé

Donald Trump wọ kóòtú dúdú, gbohùngbohùn wà níwájú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹka to n ri si aabo ilẹ America;Department of Homeland Security (DHS) ti fi orukọ ọmọ Naijiria mọkandinlọgọrin (79) lede fun bi wọn ṣe ni orukọ wọn wa ninu iwe awọn ọdaran to buru ju, wọn ni awọn ṣetan lati sọ wọn loko pada si Naijiria lẹyẹ-o-sọka.

Gẹgẹ bi DHS ṣe kede loju opo wọnlanaa ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu Keji ọdun 2026, awọn ẹsun bii gbajuẹ, gbigbe oogun oloro, ifiyajẹni, iṣeṣi-paniyan, idigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ọmọ Naijiria naa jẹbi rẹ.

Ẹri kan ti wọn fi gbe ọrọ naa lẹsẹ fi han pe lasiko ti America ṣiju le awọn to wọlu naa lọna aitọ ni ọwọ ba awọn eeyan yii, ti wọn si fi ofin mu wọn.

Wọn ba wọn ṣẹjọ bi wọn ṣe wi, ile ẹjọ si da wọn lẹbi.

Atẹjade to kede ọrọ yii lati DHS ka pe: "Ẹka DHS l'America n fi oju awọn ọdaran to buru ju han, ti wọn si jẹ ajeji, ti awọn aṣọbode ilẹ America mu labẹ ofin.

"Labẹ idari Akọwe Noem, awọn oṣiṣẹ lọkunrin ati lobinrin DHS ati ICE n ṣiṣẹ takun-takun lati mu ileri Aarẹ Trump ṣe nipa lile awọn eeyan pada siluu wọn lọpọ yanturu, bẹrẹ lori awọn to buru ju, ati awọn ajeji to wọle lọna aitọ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka loju opo wọn.

Ẹ o ranti pe lara ileri Aarẹ Trump lasiko ipolongo ibo rẹ si ipo Aarẹ America ni pe oun yoo ri I pe awọn ajeji to gbọna eru wọ ilẹ naa pada sibi ti wọn ti wa.

Latigba to si ti de ori aleefa naa lọdun 2025 lo ti n mu ileri rẹ ṣẹ pẹlu awọn ofin ọlọkan-o-jọkan to de awọn ajeji

Aarẹ ilẹ America; Donald Trump

Oríṣun àwòrán, ANNABELLE GORDON / AFP via Getty Images)

Wọnyi lorukọ awọn ọmọ Naijiria ti America pe ni ọdaran nla

Boluwaji Akingunsoye, Ejike Asiegbunam, Emmanuel Mayegun Adeola, Bamidele Bolatiwa, Ifeanyi Nwaozomudoh, Aderemi Akefe, Solomon Wilfred, Chibundu Anuebunwa, Joshua Ineh, Usman Momoh, Oluwole Odunowo, Bolarinwa Salau, ati Oriyomi Aloba.

Awọn mi-in ni: Oludayo Adeagbo, Olaniyi Akintuyi, Talatu Dada, Olatunde Oladinni, Jelili Qudus, Abayomi Daramola, Toluwani Adebakin, Olamide Jolayemi, Isaiah Okere, Benji Macaulay ati Joseph Ogbara.

Bakan naa ni wọn tun fi orukọ awọn wọnyi lede: Olusegun Martins, Kingsley Ariegwe, Olugbenga Abass, Oyewole Balogun, Adeyinka Ademokunla, Christian Ogunghide, Christopher Ojuma, Olamide Adedipe, Patrick Onogwu, Olajide Olateru-Olagbegi ati Omotayo Akinto.

Awọn miran tun ni:

Kenneth Unanka, Jeremiah Ehis, Oluwafemi Orimolade, Ayibatonyе Bienzigha, Uche Diuno, Akinwale Adaramaja, Boluwatife Afolabi, Chinonso Ochie, Olayinka A. Jones, Theophilus Anwana, Aishatu Umaru ati Henry Idiagbonya.

Okechukwu Okoronkwo, Daro Kosin, Sakiru Ambali, Kamaludeen Giwa, Cyril Odogwu, Ifeanyi Echigeme, Kingsley Ibhadore, Suraj Tairu, Peter Equere, Dasola Abdulraheem, Adewale Aladekoba ati Akeem Adeleke naa ko gbẹyin.

Orukọ ọhun tẹsiwaju pẹlu: Bernard Ogie Oretekor, Abiemwense Obanor, Olufemi Olufisayo Olutiola, Chukwuemeka Okorie, Abimbola Esan, Elizabeth Miller, Chima Orji, Adetunji Olofinlade, Abdul Akinsanya, Elizabeth Adeshewo, Dennis Ofuoma ati Boluwaji Akingunsoye.

O tun ku :Quazeem Adeyinka, Ifeanyi Okoro, Oluwaseun Kassim, Olumide Bankole Morakinyo, Abraham Ola Osoko, Oluchi Jennifer ati Chibuzo Nwaonu.