Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ oníṣòwò tó kó oògùn olóró sí ojú ara l'Ekoo

Aworan afurasi naa pẹlu patako orukọ rẹ to gbe dani, ati ṣokoto rẹ to fa si isalẹ

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n gbe ogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria , NDLEA ti mu ọmọ orilẹede Naijiria kan to n gbe ni Brazil, Uche Frankin Onyekwere, n ipapakọ ọfurufu Murtala Muhammed, Ikeja nipinlẹ Eko, fun pe o gbe o tọju egbogi oloro si oju ara rẹ ati inu bata.

Onyekwere, ẹni ọdun mẹtasdinlaadọta (47), ni ọwọ tẹ l'Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii, lasiko to fẹ wọle si Naijiria lati Brazil.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi, fi lede, o ni ẹrọ ayaworan ara lo ṣawari egbogi oloro naa lara furasi yii.

Atẹjade naa ni, " Onisowo kan to jẹ ọmọ Naijiria ṣugbọn to n gbe ni Brazil, Uche Franklin Onyekwere, ni ọwọ ti tẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport (MMIA) Ikeja, niluu Eko, fun bo ṣe gbe oogun oloro si oju ara rẹ ati inu bata to wọ.

"Lasiko ti ẹrọ ayaworan n yẹ Onyekwere wo ni a ti ṣawari awọn oogun oloro to gbe sara.

"Lẹyin eyi ni a tun ṣe iwadii rẹ, ti a si ba awọn egbogi oloro ni ara rẹ, eyi to tun so mọ itan."

Babafemi fi kun un pe egbogi oloro (cocaine) tawọn ba lara afurasi naa to iwọn 1.60 kilograms.

"A tun tẹsiwaju ninu ayẹwo naa, a si tun ri awọn miran ti afurasi yii ko sinu bata rẹ. Onyekwere jẹwọ pe oun ra oogun oloro naa ni Brazil lati wa tun un ta ni Naijiria, koun le ri owo ṣe ikomọ ọmọ tuntun toun ṣẹṣẹ bi."

"Afurasi naa n gbe ni Rua Ever, Mulariuha, São Paulo, to si ni oun ti n gbe ni Brazil lati ọdun 2008, to si n ṣe okowo iṣerẹ ọmọde fun ọdun mẹsan an."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post