Ibadan robbery: Àgbègbè Secretariat ni adigunjalè ti gba ₦446,000 lọ́wọ́ oníbàárà báńki tí wọ́n pa

Ibadan

Oríṣun àwòrán, others

Awọn adigunjale ti yinbọn pa ọkunrin kan, Taoreed Olusola, lagbegbe ọfiisi ijọba to wa ni Agodi, ni ilu Ibadan.

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi aago kan abọ ọsan ọjọ Aje.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe, ni ṣe ni awọn adigunjale ọhun ṣọ arakunrin naa lati lori alupupu, ki wọn to ṣakọlu si i.

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

O ni lẹyin naa ni wọn gba gbogbo ohun to wa lọwọ rẹ ki wọn yin in nibọn, ti wọn si gbe alupupu rẹ lọ.

Iroyin ni ile ifowopamọ kan ni awọn adigunjale ọhun ti n tọpasẹ ọkunrin naa bọ lẹyin to lọ gba owo tan.

Iwe ile ifowopamọ ti wọn ri lara oloogbe naa fi han pe o ṣẹṣẹ gba owo ti iye rẹ to ₦446,000 nile ifowopamọ kan to wa ni Bodija ni, ki wọn to kọlu.

Oṣojumi koro miran sọ pe "Wọn ṣakọlu si Taoreed nigba to n gbiyanju lati ṣa mọ wọn lọwọ pẹlu alupupu rẹ lẹba ile gomina, ṣugbọn wọn da duro wọn si yinbọn lu nigba meji lẹyin ti wọn gba owo naa tan, wọn si salọ."

O tẹsiwaju pe "Inu ọfiisi ni a wa ti a ti gbọ iro ibọn nigba meji, nigba naa ni a sare jade lati wo ohun to n ṣẹlẹ."

"Igba yẹn ni a ri awọn ọkunrin meji lori ọkada, ti wọn n gbe owo ati alupupu rẹ salọ."

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ pe oun ko ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa nitori ọwọ oun kun fun iṣẹ igbaniwọle awọn ọlọpaa tuntun to n lọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'