John Blake: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ ọdún 17 tí wọ́n ní ó pa èèyàn méjì níbi ìwọ́de Black Lives Matter ní Kenosha

Ifẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin ti awọn ọlọpaa alawọ funfun yinbọn lu jacob Blake, to jẹ alawọ dudu ni l'Amẹrika, lawọn eeyan ilẹ naa bẹrẹ si ni tu sita lati ṣe ifẹhonuhan lori iṣẹlẹ naa.

Ni alẹ ọjọ kẹta ti ifẹhonuhan naa bẹrẹ ni iroyin sọ pe ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan yinbọn lu awọn olufẹhonuhan, ti meji ninu awọn eeyan ọhun gbẹmi mi, ti ẹnikan si farapa yanayana.

Lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ofin mu nile iya rẹ ni Antioch, ni ipinlẹ Illinoi, to jẹ nnkan bi ọgbọn iṣẹju si Kenosha nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Ni bayii, wọn ni yoo foju bale ẹjọ lori ẹsun ipaniyan.

Ta ni ọmọkunrin naa gan?

Ayẹwo ti a ṣe si oju opo ikansiraẹni rẹ lori itakun agbaye fi han pe ọmọdekunrin naa, Kyle Rittenhouse fẹran awọn agbofinro.

Aworan to fi soju opo Facebook rẹ n ṣafihan akọle "Blue Lives Matter," eyii to n ṣapẹrẹ ibadọre pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa, to tun jẹ atako si awọn alatilẹyin "Black Lives Matter."

Pupọ ninu awọn akọle to maa n ko sori ikanni facebook rẹ lo maa n fi bu iyi fun awọn ọlọpaa ti wọn ku ṣenu iṣẹ, o si ti fi igba kan jẹ ara ọmọ ikọ ileeṣẹ ọlọpaa abẹle ti ẹka Grayslake ri.

Jacob Blake

Oríṣun àwòrán, @TalbertSwan

Àkọlé àwòrán, Igba meje ni wọn yinbọn lu Jacob Blake ni Kenosha

O tun fẹran ibọn lọpọlọ nitori bo ṣe maa n fi aworan ibọn soju opo ikansiraẹni rẹ lori ayelujara.

O sọ pe ara iṣẹ oun ni lati daabo bo awọn eeyan, o ni "ti eeyan ba ṣeṣe, mo le fi ara mi sinu ewu lati ran wọn lọwọ."

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Oun to ṣẹlẹ

Lalẹ ọjọ ifẹhonuhan naa, wọn ri Kyle lori aworan CCTV nibi ti awọn eeyan kan ti n le e pẹlu ibọn ti oun naa si yinbọn lu ọkunrin to n le e ni ori.

Lẹyin naa ni awọn eeyan miran tun le e pẹlu ibọn lọwọ ti oun naa si da pada fun wọn.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ̀kùnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ rèé lórí aláwọ̀ dúdú t'ọ́lọ́páá tún dàbọn bò l'Amẹrika

John Blake: Ẹ̀kùnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ rèé lórí aláwọ̀ dúdú t'ọ́lọ́páá tún dàbọn bò l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Others

Ọgbẹni John Blake, ọkunrin alawọ dudu tawọn ọlọpaa yinbọn fun ni Kenosha nipinlẹ Wisconsin wa ni wọọdu ICU nibi ti o ti n gba itọju lọwọ Ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi darukọ awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan sita, amọ awọn ọlọpaa naa ti bẹrẹ isinmi lẹnu iṣẹ ni kiakia.Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa ko ṣ'adeedee lọ si ibi iṣẹlẹ ọhún, wọn ni awọn kan lo ranṣẹ pe wọn pe ki wọn wa pẹtu si ija.

Amọ, ko si ẹni to mọ ohun to da awọn ọlọpaa ati Ọgbẹni Blake pọ.Ẹka idajọ nipinlẹ Wisconsin ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, bakan naa lọgọrọ eeyan ti buwọlu aba lati gbe awọn ọlọpaa ti ọrọ kan sile ẹjọ.

John Blake wà ní ICU, ọlọ́pàá tó yìnbọn fún un bẹ̀rẹ̀ ìsinmi tipá tipá

Oríṣun àwòrán, others

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Awọn ti ọrọ naa ṣẹlẹ loju wọn ṣalaye pe Blake n pẹtu si ija laarin obinrin meji k'awọn ọlọpaa to bẹrẹ sí ni yin taju taju.Fidio to lu ayelujara pa fihan pe Blake ko gbe ibọn dani, ṣugbọn awọn ọlọpaa tun yinbọn fún un nigba meje lati ẹyin.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Agbẹjọro ati ajafẹtọ, Ben Crump sọ loju opo Twitter rẹ pe loju ọmọdekunrin mẹta Blake lawọn ọlọpaa ti yinbọn fún un.Crump ni titi laelae ni iṣẹlẹ yii yoo maa ṣe iyọnu fawọn ọmọ naa.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ẹwẹ, oludije ipo aarẹ f'ẹgbẹ oṣelu Democrat l'Amẹrika, Joe Biden ti pe fun Iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa.

Jacob Blake

Oríṣun àwòrán, @BoringMe2Death

Àkọlé àwòrán, Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oṣu diẹ ti awọn ọlọpaa tẹ George Floyd to jẹ alawọ dudu

Awọn eeyan orilẹ-ede Amẹrika ti gunle iwọde #BlackLivesMatter lọtun lẹyin ti awọn ọlọpaa alawọ funfu yinbọn lu ọkunrin alawọ dudu kan nigba meje.

Ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Jacob Blake ti wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bayii nile iwosan.

Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Kenosha, to wa ni ipinlẹ Wisconsin lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn gba ipe gbajawiri lori wahala to waye ninu ile kan.

Fidio bi awọn ọlọpaa ṣe yinbọn lu ọkunrin ọhun ti gba ori ayelujara kan, nibi ti ọkunrin naa ti n rin lọ ṣeba ọkọ kan, to si kọyin si awọn ọlọpaa naa ki wọn to yin in nibọn.

Ileeṣẹ to n ri si eto idajọ ni Wsconsin ti ni iwadii ti bẹrẹ lori bi ọrọ naa ṣe ṣẹ, wọn si ti ni ki awọn ọlọpaa to lọwọ ninu iṣẹ ọhun lọ rọkun nile fun igba diẹ na.

Ṣugbọn awọn ara ilu Kenosha ti bẹrẹ ifẹhonuhan lẹyin iṣẹlẹ ọhun, koda wọn dana sun ọpọ ọkọ ti wọn si n pariwo pe o to gẹ.

Jacob Blake

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ko pẹ si akoko naa ti ijọba ipinlẹ ọhun kede igbele pajawiri, o si rọ awọn to n ṣowo oni wakati mẹrinlelogun lati tilẹkun ṣọọbu wọn nitori awọn kọlọrọsi to n lo iṣẹlẹ naa lati ja ṣọọbu, ti wọn si n ji ọja ko lọ.

Ẹwẹ, gomiona ipinlẹ Wisconsin, Tony Evans ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oṣu diẹ ti awọn ọlọpaa tẹ George Floyd to jẹ alawọ dudu lọrun pa l'Amẹrika yii kan naa.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'