Lagos Lockdown: Wo ìlànà tuntun ṣáájú ṣíṣí ilé ìtura, sinimá, gbọ̀ngàn ayẹyẹ ní Eko

Oríṣun àwòrán, @followlasg
Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ilana tuntun jade fun awọn olokoowo to n fi irinajo afẹ, ati faaji ṣiṣẹ nipinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Kọmisanna fun irinajo afẹ, iṣẹ ọna, ati aṣa, Arabinrin Uzamat Akinbile-Yussuf, fi sita ni opin ọsẹ, o sọ pe ilana tuntun naa kan awọn ile itura, ile gbigbe alasiko diẹ, ootẹli, gbọngan ayẹyẹ, ile ounjẹ, ile ọti, ati ile sinima.
Arabinrin Akinbile-Yussuf sọ pe awọn ilana tuntun naa, yatọ si eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ bii ọwọ fifọ ni gbogbo igba, lilo sanitaisa, titakete sira ẹni, lilo ibomu-b'ẹnu, ṣiṣe ayẹwo bi ara ṣe gbona si, fifin oogun apakokoro si ayika, ati bẹẹ bẹ lọ.
- Kọmísọ́nà ètò ìlera ìpińlẹ̀ Eko ọjọ̀gbọ́n Akin Abayomi ti lùgbàdì ààrùn Covid-19
- 'Bí a kò bá fẹ́ ìbínú Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Tinubu du ipò ààrẹ̀ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ APC ní 2023'
- Iròyìn àyọ, àdínkù tún bá iye ènìyàn tó lùgbàdì Covid -19 ní Nàìjíríà lọ́jọ́ Àìkú
- Ilé ẹrù míì tó jábọ́ l‘Eko tún mú ẹ̀mí obìnrin méjì lọ
Awọn ilana tuntun naa niyii:
- Alejo ti wọn o maa gba ko gbọdọ ju ìdá ọgọta lọ ti wọn o gba lẹẹkan naa.
- Gbogbo alejo ti ọjọ ori wọn ba ju ọdun mejidinlogun lọ gbọdọ fi ọwọ si iwe Covid-19 ni ẹnu ọna, ki wọn si kọ orukọ wọn, adirẹsi ati numba ẹrọ ibanisọrọ wọn.
- Awọn gbọngan ayẹyẹ gbọdọ ni iwe ẹri ti ijọba ipinlẹ Eko fun wọn ṣaaju ki ayẹyẹ kankan o to waye nibẹ, to fi mọ ontẹ ajọ to wa fun ọrọ abo nipinlẹ Eko.
- Fun awọn gbọngan ayẹyẹ bakan naa, awọn ti yoo joko fun ayẹyẹ ko gbọdọ ju ìdá aadọta lọ, asiko ti wọn yoo lo nibẹ ko si gbọdọ kọja wakati mẹta.
- Wọn gbọdọ to tabili takete si ara wọn pẹlu mita marun-un, bẹẹ ni awọn ijoko gbọdọ jina sira wsn ni iwọn mita meji.
Arabinrin Akinbile-Yussuf sọ pe miliọnu kan Naira ni ẹnikẹni to ba ru ofin yii yoo san gẹgẹ bi owo itanran.
Ilana fun awọn ile sinima

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Fun awọn ile sinima, wọn gbọdọ ri i daju pe eero iworan ko ju ìdá aadọta lọ lẹẹkan naa, ti wọn si gbọdọ fi ọwọ si iwe akọsilẹ nipa Covid-19.
Kọmisanna fi kun pe awọn ile sinima ko gbọdọ ṣi ilẹkun wọn tayọ aago mẹrin idaji si mẹwaa alẹ, ni ibamu pẹlu ofin isede to wa nita.
Laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ eko kede pe awọn ile ijọsin le di ṣiṣi pada lẹyin bi oṣu maarun ti wọn ti wa ni titi pa nitori aarun coronavirus.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ti ibùdó ìtọ́jú ààrùn Covid-19 tó wà ní Eti-Osa
Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe ilẹkun ibudo iyasọtọ awọn alarun Covid-19 to wa ni Eti-Osa ti pa.
Gomina Babajide Sanwo-Olu lo sọ igbesẹ naa di mimọ lọjọ Satide, lasiko to n ba awọn araalu sọrọ lori ibi ti nkan de duro nipa aarun naa nipinlẹ Eko.
Gomina fi kun ọrọ rẹ pe laipẹ ni wọn yoo tun ti eyi to wa ni Agidingbi, ti wọn o si ko awọn alaarun naa lọ si ibudo nla tuntun IndoCentre, ti wọn ṣẹṣẹ kọ si adugbo Anthony.
Àwọn ilana tuntun ti ijọba Eko la kalẹ fun awọn ara ilu lori Covid-19
Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣe sọ ọ lọjọ abamẹta, O ni ki awọn ara ipinlẹ Eko fi sọkan pe aridaju akọsilẹ n wa pe bi eeyan pupọ ba korajọ, o lee dakun aranka arun Covid-19.
Sanwo-Olu ni awọn ile ijọsin yoo di ṣiṣi pada fun awọn Musulumi ati Kristẹni ṣugbọn ida aadọta ninu ọgọrun pere ni wọn faaye gba.
Lafikun o ni awọn ṣọọsi to jẹ pe ọjọ Satide ni wọn maa ṣe isin naa lanfani lati bẹrẹ pada ṣugbọn ni itẹle ofin ti awọn ti ọjọ aiku naa n tẹle ni o.
O ni ẹẹkan lọsẹ nikan ni awọn ile ijọsin lanfani lati pe jọ pọ ti wn si lee ko isin pupọ jọ loojọ bi wọn ba ṣaa ti tẹle ofin aadọta olujọsin.
Ẹwẹ, o ni wọn lee gba awọn eniyan niyanju ti wọn ba nifẹ si wiwo isin naa lori ayelujara lati ṣe bẹẹ.
Yatọ si eyi, anfaani ti wa fun ipejọpọ ita gbangba bi ipade, lati gba to aadọta eyan, dipo ogún ti ijọba pa laṣẹ tẹlẹ.
Gomina Sanwo-Olu tun kede pe awọn ile ounjẹ yoo bẹrẹ si ni fi aaye gba awọn onibaara wọn lati joko jẹun.
Awọn ileewe girama ti ijọba ati aladani yoo di ṣiṣi pada fun awọn akẹkọọ to fẹ ẹ ṣe idanwo aṣejade.
Ko ti i si aaye fun awọn ibudo igbafẹ bi i ile ọti, ile iworan bọọlu ati ibudo ti wọn ti n ṣafihan sinima lati bẹrẹ iṣẹ pada.
Amọ o, gbogbo awọn ti ijọba ti fun ni anfaani lati bẹrẹ iṣẹ wọn pada gbọdọ ma a tẹle awọn ilana bi i titakete siraẹni, lilo ibomu, ati ọwọ fifọ.
Yatọ si awọn ilana tuntun yii, gomina tun kede pe o ti le ni ẹgbẹrun mẹẹdogun eeyan to ti ni coronavirus ni ipinlẹ Eko.















