Ebenezer Obey fi ìkéde síta pé òun n gbèèrò láti gbé ìyàwó tuntun,

ebenezer obey

Oríṣun àwòrán, Instagram/ebenezer obey

Eekan olorin ti gbogbo agbaye mọ ni Oloye Ebenezer Obey jẹ.

Iroyin iku rẹ to kaakiri laipẹ yii fihan bi agba olorin Juju naa ṣe lokiki si, nitoripe kaakiri agbaye ni awọn eeyan ti n beere pe ṣe lootọ ni tabi irọ.

Amọṣa, ṣe awọn agba bọ, wọn ni baoku iṣe o tan.

Nibayii lẹyin ti o ti han gbangba pe agba orin yii ko jade laye gẹgẹ bi awọn kan ṣe sọ, baba funrarẹ ti jade sita pe o ṣeeṣe ki iyawo tuntun o wọle laipẹ o.

Ẹyin naa ni haa, baba Ebenezer Obey ṣalaye ọrọ yii ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria.

"Ohun to dara ni ki iyawo wa pẹlu eniyan, ko si tako ofin Ọlọrun...obinrin to ti to ọgọta ọdun ni iru emi bayii n wa, nigba ti mo ba si ṣe e laipẹ, gbogbo aye ni yoo ri."

Nigba ti Ebenezer Obey n sọrọ lori irufẹ obinrin to fẹ, o ṣalaye pe oun ko wa obinrin ti yoo tun maa bimọ mọ bayii bikoṣe nitori ati lee jọ maa wa pọ.

Àkọlé fídíò, Owu Water Fall: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì

"Mo ti lọmọ, ọmọ-ọmọ ati ọmọ-ọmọ-ọmọ, Ọlọrun ti bukun mi"

O ṣalaye pe "oponu agbalagba ni yoo ma a gbeero lati fẹ ọdọmọbinrin, nibi ti ọjọ ori mi de bayii".

Obey sọ pe iru ọdọmọbinrin bẹ ẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ aye ni, to si l'agbara ibalopọ ati okun.

Lara awọn amuyẹ ti iyawo ti baba fẹ ẹ fẹ gbọdọ ni, ni pe yoo ti to ẹni ọgọta ọdun tabi ju bẹẹ lọ, kii sii ṣe nitori ọmọ bibi mọ.

Agba akọrin Juju miliki naa ṣalaye siwaju pe ohun kii ye ṣe afẹri iyawo oun to jade laye ti oun si maa n rii loju ala.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2011, ni iyawo Ebenezer Obey, Ajinhinrere Juliana Obey-Fabiyi kú lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin.