Sunny Ade: Ebenezer Obey sọ pé onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn ni

Oríṣun àwòrán, @KingSunnyAde70
Yoruba ni ọdọọdun la n ri orogbo, ọdọọdun la n ri awusa, ọdọọdun la n ri ọmọ obi lori atẹ.
Ọdun miran tun ti ko fun ilumọọka olorin juju nni, Oloye Sunday Adeniyi Adegẹye, ti gbogbo eniyan mọ si King Sunny Ade.

Oríṣun àwòrán, @KingSunnyAde
Ọjọ Satide, ọjọ kejilelogun osu kẹsan ọdun 2018 ni Sunny Ade pe ẹni ọ̀dun mejilelaadọrin loke eepẹ, ti ọpọ eeyan si ti n ki ku oriire, eyi ti ko yọ BBC Yoruba silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kin lẹ fẹ mọ nipa Sunny Ade?
- Ilu Osogbo nipinlẹ Ọsun ni wọn bi Sunny Ade si, bi o tilẹ jẹpe idile ọba nilu Ondo lo ti wa, eyi ti wọn fi n pe ni Ọmọọba
- Ọjọ kejilelogun osu kẹsan ọdun 1946 ni wọn bi Sunny Ade
- Atẹduuru ijọ ni baba rẹ, nigbati iya rẹ jẹ onisowo latilu Akurẹ
- Ọdọ Moses Ọlaiya Adejumọ, taa mọ si baba Sala ni Sunny Ade ti bẹrẹ isẹ
- Ọdun 1967 lo da ẹgbẹ orin tiẹ silẹ, to si pe ni Green Spots
- Tunde Nightingale ni awokọse fun Sunny Ade
- Sunny Ade lee lo ọpọlọpọ ohun eelo ikọrin fun orin juju to n kọ
- Osu kẹta ọdun 2017 ni minisita feto iroyin, Alhaji Lai Muhammed fi Sunny Ade jẹ asoju feto iyipada rere ni Naijiria
- Suuny Ade ni Olukọ olubẹwo fun fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu ile Ifẹ
- O tun da ileesẹ redio kan silẹ ni ilu Ondo
- Ijọba fi ami ẹyẹ nla ni orilẹede yii ti wọn pe ni Order of the Federal Republic, da Sunny Ade lọla
- Sunny Ade maa n sere tiata, to si ti kopa pẹlu awọn osere Hollywood tilẹ Amẹrika lọdun 1986 ati 1987
- Sunny Ade ti gba onirruru ami ẹyẹ miran yatọ si ti ilẹ wa, to si gba ami ẹyẹ AFRIMA losu kọkanla ọdun 2016.

Oríṣun àwòrán, @KingSunnyAde
Ebenezer Obey ki Sunny Ade ku oriire ọjọ ibi
Ebenezer Fabiyi Obey, ti gbogbo eeyan mọ si Obey, ti wa ransẹ ikinni ku oriire ọdun tuntun miran si akẹẹgbẹ rẹ nidi orin kikọ, Sunny Ade.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Obey ni "Oniwa irẹlẹ, ọlọpọlọ pipe ẹda ati ẹni iyi kaakiri agbaye ni King Sunny Ade, mo si gbadura pe Ọlọrun yoo fun ni ẹmi gigun ati alaafia lati se ọpọ ọdun laye."









