BB Naija: Yàtọ̀ sí Lecon, àwọn olóríire yòkúù ni Katung Aduwak, Efe Ejeba, Miracle Igbokwe, Mercy Eke

Oríṣun àwòrán, others
Eruku sọ nigba ti wọn kede Olamilekan Agbelesebioba,'Laycon' gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto igbe aye aladani lori amounmaworan ta mọ si BB Naijia.
Abala karun eto naa leyi to wa sopin yii, ta mọ si Season 5 Lockdown.
Awọn eniyan mejila si mọkanlelogun lo maa n kopa, ti wọn o si maa lo igbe aye wọn ojoojumọ loju gbogbo aye, lati gba ẹbun owo nla ati awọn nkan iyebiye miran.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn afọbajẹ wọ́ Oluwo relé ẹjọ́, ìjọba Osun kò tíì fọùn
- Ẹ gbà mí, Nàíjíríà gbá mi lórí àyẹ̀wò Covid-19 - Iyabo Ojo figbe ta
- A ti ja aráàlú kulẹ̀, ta bá pè wọ́n fún ìwọ́de, wọn kò ní jẹ́ wa mọ́ - NLC Eko
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò fi ní bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì mọ́ lónìí
- Ẹgbẹ́ òkùnkùn yìnbọn lu ọmọ kan ní ikùn lásìkò ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn
- Laycon ni ọmọ ológo tó jáwé olúborí ní ètò BBNaija season 5 'Lockdown'
- Kí ló wà láàrin Olorì Badra àti Bobrisky, tí ọ̀rọ̀ wọn fi wọ̀?
- Wo ọ̀nà àbáyọ sí bo ṣe ń han‘run
Lati jawe olubori, awọn olukopa gbọdọ ri eniyan to pọ to, lati dibo fun wọn lati ni ibo to ga julọ.
Bi apa karun un eto naa ṣe ti wa sopin bayii, agbeyẹwo awọn to ti jawe olubori lati ẹyin wa ree, pẹlu iye ẹbun owo ti wọn mu lọle.

Oríṣun àwòrán, LAYCON/INSTAGRAM
Katung Aduwak: Olubori akọkọ lọdun 2006
Isọri kinni BB Naija ti wọn kọkọ se ni Naijiria waye ni ọjọ karun un, oṣu kẹta titi wọ ọjọ kẹrin, oṣu keje, ọdun 2006.
Lasiko naa, wọn pe e ni Big Brother Nigeria. Michelle Dede ati Olisa Adibua, lo ṣe atọkun eto naa.
Ninu eto naa ni Katung Aduwak, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti jawe olubori nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Katung Aduwak
O gba ẹbun owo ẹgbẹrun lọna ọgọrun un dọla ($100,000).
Lẹyin naa o ti ṣe daada funra rẹ, o gba oye ọmọwe ninu ẹkọ bi a ṣe n ya fiimu igbalode ni Digital Film Academy ni New York.
Ni bayii, atọkun ati adari ere ni isẹ to yan laayo, ti o si ti se awọn sinima bii "Unwanted Guest" ati Heven's Hell".
Bakan naa lo dari oniruuru awọn fọnran orin fun ile isẹ Chocolate City, Styplus, Gabriel Afolayan.
O tun kopa ninu awọn ere agbelewo EbonyLife ati "Desperate Housewives"

Oríṣun àwòrán, others
Michael Efe Ejeba: Oloriirelọdun 2017
O le ni ọdun mẹwaa lẹyin ti wọn se apa kinni, ki wọn to ṣe apa keji ti wọn wa bẹrẹ si ni pee ni Big Brother Naija.
Wọn pe akọle eyi ni "See Gobe", ti wọn si ṣe afihan rẹ ni inu oṣu kinni, ọdun 2017, eniyan mejilelogun lo kopa, ti wọn si fẹ gba miliọnu marundinlọgbọn Naira.
Ebuka Obi-Uchendu to kopa ninu apa kinni eto naa lo se atọkun eto, nigba ti Efe Ejeba si jawe olubori lasiko naa.
Lẹyin to jawe olubori ninu eto naa, o lọ si ipinlẹ Jos lati ipinlẹ Eko lati lọ bẹrẹ iṣẹ orin gẹgẹ bi iṣẹ to yan laayo.
O gbe awo kan jade to pe akọle rẹ ni EP Lagos, bakan naa lo ba ilumọọka Olamide kọwọrin ninu orin ti akọle rẹ jẹ "Warri."
O ṣe awọn awo orin miran jade, o ṣi n tẹsiwaju lati maa kọ orin titi di asiko yii.

Oríṣun àwòrán, others
Miracle Igbokwe: Olubori lọdun 2018
Ọdun 2018 ni wọn ṣe apa kẹta eto BBNaija pẹlu akọle "Double Wahala".
Ebuka naa lo tun ṣe atọkun eto naa bakan naa fun ọsẹ mejila gbako, ti wọn fi ṣafihan eto naa.
Akopa ogun lo peju fun eto naa ti wọn ni afoju sun lati gba ẹbun miliọnu marundinlọgbọn naira bakan naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/miraclenaija
Lẹyin o rẹyin Miracle Igbokwe lo pada gbe gba oroke, ti o si gba ẹbun owo tabua ọhun lọle.
Wọn gbe ọkọ bọgini Hyundai Tuscon fun un, pẹlu sọwedowo miliọnu marunlelogun Naira, eroja amule ṣeringindin to to miliọnu mẹta fun un.
Pẹlu irinajo eniyan meji lọ si ibi to larinrin ti owo rẹ yoo to miliọnu marundinlaadọta Naira.

Oríṣun àwòrán, Twitter/miraclenaija
Bakan naa ni Miracle gba ẹbun owo miliọnu kan naira lati ọdọ Payporte Arena Games ati ẹgbẹrun lọna igba naira lati ọdọ Final Wager.
Bakan naa lo jẹ ẹbun Pepsi Fresh your mix, to si pese miliọnu kan naira ati irinajo lọ si Dubai fun ayẹyẹ Africa Music Fest, ati ipese Pepsi ati Aquafina fun odindin ọdun kan.
Lẹyin to jawe olubori lori eto yii lo mori le ile ẹkọ olukọni nipa bi a ṣe n wakọ ofurufu ni orile-ede South Africa, lati kọju mọ iṣẹ to yan laayo.
Lọdun 2019, Miracle gba iwe ẹri gẹgẹ awakọ ofurufu. "Instrument Rated"

Oríṣun àwòrán, others
Mercy Eke: Oloriire tọdun 2019
Apa kẹrin BBNaija ni akọle rẹ n jẹ "Pepper Dem" bẹrẹ ni ọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun 2019.
Yatọ si bi awọn ti isaaju ni orilẹ-ede Naijiria, wọn lo ọjọ mọkandinlọgọrun un ninu ile naa.
Awọn mẹrindinlọgbọn lo peju sibẹ, ti ẹni to jawe olubori si gba ẹbun to to ọgọta miliọnu Naira.
Lasiko yii ni wọn gbe owo ẹyọ Bet9ja wọọ, gẹgẹ bi owo ti wọn o maa na ninu ile ẹlẹgbọn ọn agba.
Mercy Eke lo jawe olubori eto naa lọdun to koja, oun ni obinrin akọkọ to jawe olubori ninu eto BBNaija lati gba ti won ti bẹrẹ.
O gba ẹbun to le ni ọgọta miliọnu Naira, ọgbọn naira lo jẹ ẹbun owo, ẹgbẹ marundinlọgbọn naira ni moto bọginni Innoson ti wọn gbe fun, bakan naa lo rinrin ajo lọ Dubai pẹlu awọn miran.
Mercy gba ami ẹyẹ Africa Magic Viewers Choice gẹgẹ bi ẹni to n mura daradara julọ ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọsun 2020. O ra ile kan si Lekki, nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Twitter/real_mercyeke
Oun ati ololufẹ rẹ lasiko ti wọn wa nile ẹlẹgbọn agba Ike ti lọ da eto tiwọn naa kalẹ ti wọn n pe ni "Mercy & Ike ".
O ti ṣe agbekalẹ ile iṣẹ to n tale talẹ to si pe orukọ rẹ ni Lambo Homes.
Ni ibẹrẹ ọdun yii ni Mercy ke gbajare pe o wu oun lati pada si igbeaye oun tẹlẹ nitori oniruuru ojuse lo wa ninu ki eniyan jẹ ilumọọka.













