Secret Cults in Nigeria: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó yìnbọn

Aworan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Ogun State

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Black Axe kan to n ṣe idaro akẹgbẹ wọn ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ nilu Ogijo, nipinlẹ Ogun.

DSP Abimbola Oyeyemi to jẹ alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita fawọn akọroyin.

O ni awọn mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa, lẹyin ti eeyan kan lọ fẹjọ sun lagọ ọlọpaa pe wọn yinbo lu ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan ni ikun.

Oyeyemi ni ibọn yinyin naa waye lasiko tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n ṣe iwọde idaro akẹẹgbẹ wọn to ku.

Aworan eto igbani wọle sẹgbẹ okunkun
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ọna ni eto igbani wọle maa n gba ninu awọn ẹgbẹ okunkun

Yatọ si pe wọn yinbọn lu ọmọkunrin naa nikun, wọn tun gba foonu ọwọ rẹ, ti wọn si tun soro fawọn aladugbo pẹlu.

Lẹyin ti awọn ọlọpaa doju ija kọ awọn afurasi ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun naa tan, ni ọwọ ba tẹ wọn.

Eeyan mẹjọ ni awọn afurasi ti ọlọpaa mu, ti ọjọ ori wọn si wa laarin ogun ọdun si mejilelọgbọn, ọkunrin si ni gbogbo wọn.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolowo Ajogun ti wa paṣẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa.

Ọmọkunrin ti wọn ti wọn yinbọn lu ti n gba itọju nile iwosan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aworan Bobosky

Oríṣun àwòrán, Others

Bí ògbójú ọlọ́sà ajínigbépawó, Bobosky ṣe kú sí àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers pawọpọ pẹlu awọn fijilante ibilẹ lati fi mu igara ọlọsa agbenipa kan to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Greenlanders, Honest Diigbara ti ọpọ mọ si Bobosky.

Sugbọn ko pẹ si akoko ti wọn gba a mu lo ku si wọn lọwọ lahamọ ọlọpaa ti wọn fi si.

Wọn kede iku igara ọlọsa ajinigbepawo Bobosky ti wọn mu lọjọ Abamẹta.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Rivers Nnamdi Omoni to fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC sọ pe oro ọta ibọn lo ṣokunfa iku rẹ.

Mọjumọ Abamẹta ni wọn lawọn mu ni adugbo Korokoro nibi to sapamọ si pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ.

Ninu fọnran fidio kan taa ti ri bawọn ọlọpaa ṣe gba mu, niṣe ni ẹjẹ wa lara Bobosky torukọ rẹ gangan n jẹ Honest Digbara.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ṣé lóòtọ́ ni pé fijilanté àti àwọn ọlọ́pàá ti mú Bobosky?

Ọwọ palaba igara ọlọṣa ajinigbe kan ti n dẹru ba ara ilu ni ipinlẹ Rivers la gbọ pe o ti segi lẹyin tọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ.

Honest Digbara ti inagijẹ rẹ Bobosky fẹ fara pẹ orukọ gbajumọ nii, Bobrisky la gbọ pe awọn ọlọpaa mu ni nkan bi ago meji abo oru ni adugbo Korokoro Tai ni ijọba ibilẹ Gokana.

Digbara ni ọga awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Greenlander ni ipinlẹ Rivers.

Awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria kan naa sọ pe igbakeji rẹ faragbọta ninu ikọlu pẹlu awọn ọlọpaa.

Ṣaaju asiko yi, Gomina Nyesom Wike ti kede ọgbọn miliọnu naira gẹgẹ bi ẹbun fẹnikẹni to ba ri Digbara mu.

Agbarijọpọ awọn agbofinro ti ọga ọlọpaa Gokana dari wọn ati ọmọ ikọ fijilanti ni wọn jijọ mu ọdaran yi.

Akọroyin kan,Awajis George fi fọnran fidio ibi ti awọn ọlọpaa ti mu afurasi yi sita loju opo Twitter