Northern Youths in Lagos: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàṣẹ fún ikọ̀ fijilańté láti wá àwọn ọ̀dọ́ àríwá tó dìhámọ́ra jáde

Oríṣun àwòrán, Others
Jinni-jinni ti da wo awọn olugbe ipinlẹ Eko bayii nitori aworan awọn ọdọ kan ẹkun ariwa ilẹ yii, ti wọn dihamọra pẹlu ibọn.
Aworan naa, to gba ori ayelujara kan, to n kọ ọpọ eeyan lominu, lo mu ki ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede ayẹwo ikọ naa.
Ibẹrubojo yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti ọkunrin fi aworan soju opo ayelujara nipa awọn ọdọ ariwa Naijiria to n ya wọlu Eko, ti wọn si ni ibuba ti wsn fori pamọ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Nàíjíríà ti pín yẹlẹyẹlẹ láyé Buhari, ìjákulẹ̀ dé! - Obasanjo gbarata
- Olùkọ́ mi ń bá mi lòpọ̀ kí ń le yege ìdánwò WAEC - Akẹ́kọ̀ọ́ l‘Ogun
- Olólùfẹ PDP 18 kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ lásìkò tí wọn ń lọ pàdé gómìnà
- Iyabo Ojo ṣílé, Toyin Abraham fẹ́ ṣílé iṣẹ́ f'ọmọ, àtàwọn nǹkan míràn lágbo òṣéré
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
- Wo ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta tó ti pé ọdún 48 tó ń ṣe ìdánwò WAEC, kó le di nọ́ọ́sí
Ọkunrin naa ninu alaye rẹ lori ayelujara ni oun gun ọkada lọ si adugbo ELF lọna Ajah ni Lagos Island, ti awọn si pade ọdọ apa oke ọya miran marun, tawọn naa gun ọkada.

Oríṣun àwòrán, Others
O ni ọlọkada toun si apo rẹ, to si ko asọ 'vest' ti wọn kọ 'Gallante Vigilante, Makoko Division‘ si lara, eyi to n sọ pe filante adugbo makoko ni wọn.
Awọn ọdọ naa wọ asọ yii, ti ọlọkada oun si ja oun silẹ nibi toun n lọ, to si sẹri pada.
Ọkunrin naa ni ara fu oun, ti oun si mu ọkada miran lati tọpasẹ rẹ lọ sinu ile akọpati kan ti banki Zenith n kọ lọwọ ni ilegbe ELF, ti oun si ri pe awọn ọdọ lati oke ọya to wa ninu ile naa le ni aadọta.
O ni oun ri Asọna abawọle ilegbe ELF naa ati ọlọkada oun akọkọ ti wọn n takurọsọ, nibẹ si ni oun ti kọkọ ya aworan ti oun ju sori ayelujara.
O dabi ẹni pe ọlọkada akọkọ naa fi iwe idanimọ kan han Asọna ọhun, ti onitọun si gba pe ko wọle sinu ọgba awọn ilegbe Elf yii.
O wa n beere pe ki lo de ti ẹnikan yoo fi wọ asọ vijilante adugbo Makoko, ti yoo si wa ni adugbo Lekki, nitori Makoko jinna si Lekki?
Bakan naa lo ni ọlọkada oun akọkọ ni ẹrọ afẹfẹ tajutaju kekere ati ọbẹ lara, nigba ti ọlọkada miran ni ibọn ilewọ.
O ni o da oun loju pe ipade ni awọn ọdọ apa oke ọya naa n se ninu ile akọpati naa, eyi to tumọ si pe se ni wọn fọn kaakiri ipinlẹ Eko, o si yẹ ka fura.
Ọrọ ọkunrin yii ti wa de setigbọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, to si ti pasẹ fun awọn ẹsọ to n gbogun tiwa ibajẹ lati sawari awọn ọdọ naa.
Ọwọ́ tẹ ọmọ ẹgbẹ́ ISIS 2 ní Abuja

Oríṣun àwòrán, @AsoRock
Ọjọ gbogbo ni ti ole, amọ̀ ọjọ kan soso pere ni ti olohun. Bẹ́ẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ adúnkookò-mọ́ni ISIS méjì, tí ọwọ́ pálábá wọn ségi nílu Abuja.
Ìròyìn náà ní, òkété bórù mọ́ Bashiru Adams ati Rufai Sajo lọwọ̀ nigbati àwọn òsìsẹ́ àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS gba wọn mu ni abule Kukuntu, lagbegbe Gwagwalada nilu Abuja.
Ọpọ ohun ija oloro ni wọn gba lọwọ awọn afurasi naa
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti osisẹ́ kan fun ajọ DSS, Tony Opuiyo fisita ti wi, awọn afurasi ọhun ni wọn kẹ́ẹ́fin pe wọn ti n dete lati tun se isẹ ọwọ wọn, nifọwọ sowọpọ pẹlu ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ti wọn si tun fẹ pa awọn alaisẹ ọmọ orilẹede yii lẹkun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Atẹjade naa fi kun pe, ọwọ tun tẹ diẹ́ lara àwọn afurasi agbesunmọ̀mi naa ni ipinlẹ Edo, Benue ati Cross River.
Lara awọn ohun ija oloro ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi naa ni ibọn AK 47, ọ̀ta ibọn ibọn ilewọ atawọn eroja oloro mii loniran-nran.














