Èèyàn 150 tí wọ́n tún pa lábúlé kan ní Sudan di ariwo làgbàáyé

Aworan oku eeyan rẹpẹtẹ ti wọn fẹẹ sin

Oríṣun àwòrán, ISLAND STATE RESIDENTS

O kere tan, eeyan ti ko din ni aadọjọ (150) ni a gbọ pe awọn alatako ti pa labule kan l’Aarin gbungbun Sudan.

Ohun ti a gbọ ni pe o ti le lọdun kan bayii ti awọn RSF to n koju ijọba ti n gbiyanju lati gba akoso orilẹ-ede naa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn RSF yii ko ti i sọ ohunkohun nipa pipa aadọjọ eeyan labule yii, l’Ọjọbọ, ọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun 2024 yii, wọn kede pe awọn kọlu ibudo ologun meji to jẹ tijọba.

Oku eeyan rẹpẹtẹ ti wọn tẹ kalẹ lati sin niluu Wad al-Nourah lo han ninu fidio ikọlu yii to n ja ran-in lori ayelujara.

Idi ti wọn fi f’ọpọ ẹmi alaiṣẹ ṣofo bayii ko ti i ye ẹnikẹni, ṣugbọn awọn eeyan fura si awọn RSF, wọn ni ikọlu meji lo wa lati ọwọ wọn.

Ọkunrin kan, Hafiz Mohamad, to jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan ninu ẹgbẹ Justice African Sudan, sọ fun BBC pe awọn eeyan kan ti di awati latigba ti ikọlu naa ti waye.

O ni o ṣoro lati ka iye eeyan ti wọn ti pa pẹlu, nitori wọn ṣi wa nibẹ.

Ijọba Sudan ti waa beere iranlọwọ awọn orilẹ-ede agbaye lati koju iṣoro yii.

Loṣu kejila ni ikọ RSF gba akoso ipinlẹ Gezira, eyi ti i ṣe Guusu Khartoum, Olu ilu Sudan.

Awọn eeyan n fẹsun kan ikọ yii pe wọn doju ija kọ araalu, ṣugbọn wọn ni ko sohun to jọ bẹẹ.

Bi wọn ṣe wa n jiyan pe ko ri bẹẹ yii, bẹẹ ni ija n waye laarin ikọ to n ja fun ijọba ati awọn RSF niluu El Fasher, lapa Iwọ-Oorun Sudan.

Ni bayii, o ti to ẹgbẹrun mẹẹẹdogun eeyan (15,000) ti akọsilẹ fi han pe wọn ti pa latigba ti ogun ti bẹrẹ loṣu kẹrin ọdun 2023.