Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba yóò san N105,000 gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù tuntun? - Iléeṣẹ́ Ààrẹ ṣàlàyé

Aworan Minisita eto isuna, Wale Edun ati Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency Nigeria

Ileeṣẹ Aarẹ orilẹede Naijiria ti ni irọ ni iroyin kan to ni Ijọba apapọ n gbero lati san N105,000 gẹgẹ bii owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ.

Oludamọran fun Aarẹ, Bayo Onanuga lo kede eyi loju opo ayelujara X lọjọbọ, ọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun 2024.

Iroyin ofege nipa owo oṣu naa lo gbode ti Minisita fun eto isuna lorilẹede Naijiria, Wale Edun gbe ilana ti wọn ti ṣeto silẹ fun sisan owo oṣu ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ n bere fun.

Ebun fidi rẹ mulẹ pe ti eto ti awọn ṣe kalẹ ti wa niwaju Aarẹ, to si rọ awọn araalu lati ma jaya lori ohunkohun nipa iye ti ijọba fẹ san fun awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo oṣu tuntun to kere julọ.

Aworan ohun Bayo Onanuga gbe sori ayelujara X

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ninu ọrọ ti Bayo Onanuga gbe soju opo ayelujara X o ni; “Minisita eto iṣuna ati aato ọrọ aje ni Naijiria ko fi igba kankan kede sita pe ijọba apapọ yoo san N105,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere ju fun awọn oṣisẹ.

“Iroyin to n lọ kaakiri nipa owo oṣu jẹ iroyin ofege.”

Bẹẹ ba gba gbe, Apapọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ kede pe awọn ti fi opin si iyanṣẹlodi alainigbedeke ti wọn n ṣe lọwọ lọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2024.

Ọjọ aje, ọjọ kẹta oṣu kẹfa ni iyanṣẹlodi ọhun bẹrẹ, lẹyin ti ijiroro laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba ko so eso rere, lori owo oṣu tuntun.

Iyanṣẹlodi naa mu ki ẹka ọrọ aje, ilera, irinna ọkọ ofurufu, ẹkọ, ati awọn miran dẹnukọlẹ.

Ni alẹ ọjọ Aje ni ijọba apapọ kede pe oun ti gba lati san ju ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira ti oun n dunadura rẹ tẹlẹ.

Ìjọba àpapọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Minisita eto iṣuna ati aato ọrọ aje ni Naijiria, Wale Edun ti lọ jọwọ iwe alakalẹ ṣiṣe amusẹ ọrọ owo osu oṣisẹ to kere julọ fun Aarẹ Bola Tinubu.

Minisita ọhun lo kọwọrin pẹlu minisita aba eto isuna, Atiku Bagudu nibi ti wọn ti lọ gbe iwe naa kalẹ fun Aarẹ nilu Abuja.

Lẹyin ipade naa, o ṣalaye pe agbekalẹ iwe naa ti wa lọdọ Aarẹ pelu ọrọ idaniloju pe ko sewu rara.

Igbesẹ ti Edun gbe yi ni ko sẹyin gbedeke asiko wakati mejidinlaadọta ti Aarẹ Tinubu fun un lọjọ Isẹgun.

Nibi ipade idunadura ti ikọ ijọba apapọ atawọn aṣoju ẹgbẹ awọn oṣisẹ ṣe lori ọrọ owo oṣu oṣisẹ tuntun ọhun ni akọwe ijọba apapọ, George Akume, dari.

Awọn mii to tun wa nibi ipade naa ni minisita eto iṣuna, minisita aba eto iṣuna, minisita ọrọ iṣẹ ṣiṣe minisita eto iroyin ati awọn adari ile isẹ elepo bẹntiro ilẹ Naijiria.

Tẹẹ ba gbagbe pe lọjọ Aje ọsẹ yi ni apapọ ẹgbẹ osisẹ, NLC ati TUC bẹrẹ iyansẹlodi jakejado ilẹ Naijiria.

Lati beere fun alekun owo oṣu wọn ati bi ayipada yoo ti gori owo ina mọnamọna ti wọn sẹsẹ ṣe afikun rẹ.

Ẹwẹ, lọjọ Isẹgun ni awọn adari ẹgbẹ oṣisẹ dẹwọ iyansẹlodi ọhun fun ọjọ marun-un.

ẹgbẹ oṣiṣẹ gbe igbesẹ yii lẹyin ti wọn ti fọwọ si iwe adehun pẹlu ijọba apapọ lati pada sẹnu idunadura, ti owo oṣu tuntun yoo si fojuhan laarin ọsẹ kan.