Àdó olóró Israel balẹ̀ sílé ẹ̀kọ́ ní Gaza, èèyàn 35 kú, ọ̀pọ̀ àwọn míì farapa

Oríṣun àwòrán, AFP
Ado oloro oju ofurufu orilẹede Israel kan ti ṣekupa eeyan ti ko din ni marundinlogoji ni Gaza.
Iroyin ni ile ẹkọ kan ti awọn ọmọ ogunlende n lọ, eyii ti ajọ isọkan agbaye UN, n ṣakoso rẹ ni ado oloro naa kọlu.
Awọn akọroyin abẹle fi to BBC leti pe ọkọ ofurufu ologun kan lo ju misaili lati oke si awọn yara ikẹkọọ awọn ọmọ naa to wa ni Nuseirat.
Awọn fidio to tẹle iṣẹlẹ ọhun ṣafihan yara ikẹkọọ to dawo atawọn oku eeyan.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Israel ti sọ ṣaaju pe ile kan ti oun gbagbọ pe awọn ọmọ ogun Hamas wa loun sọ ado oloro si, eyii to ṣekupa nnkan bii ogun si ọgbọn lara awọn ọmọ ogun naa.
Ijọba Gaza, ti Hamas n dari sọ pe ọrọ ti Israel sọ ko ri bẹẹ nitori ṣe ni o mọọmọ gbẹmi awọn alaiṣẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Olori aṣoju ajọ UN to n ṣakoso ile ẹkọ naa ti juwe iṣelẹ ọhun gẹgẹ bii eyii to buru jai.
Wayi o, wọn ti gbe awọn to ku atawọn to farapa nibi iṣelẹ naa lọ sile iwosan al-Aqsa Martyrs niluu Deir al-Balah to ti n gbalejo awọn to farapa latari awọn ikọlu to n waye nibẹ ṣaaju.
A gbọ pe ile ẹkọ ti ado olooro naa kọlu lo kun fun ọpọlọpọ awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ ogunlende lati Gaza.
Ṣaaju lawọn eeyan agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ti kọkọ sọ pe ogun eeyan lo jade laye.
Amọ lẹyin naa lawọn oṣiṣẹ ile iwosan al-Aqsa sọ fun akọroyin BBC pe oku eeyan ogoji lawọn ti gba lati ile ẹkọ ọhun.















