Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Yetunde Longe, obìnrin àkọ́kọ́ tó gba ipò Akọ̀wé ọlọ́pàá ní Nàìjíríà

Yetunde Longe

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, AIG Longe Yetunde ti figba kan jẹ Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ati Bauchi.

Ọga agba ọlọpaa ni Naijiria, Kayode Egbetokun, ti yan AIG Yetunde Longe gẹgẹ bii obinrin akọkọ fun ipo Akọwe ọlọpaa lorilẹ-ede yii.

Ninu atẹjade kan ti agbenusọ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, fi sita l’Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Kẹfa, ọdun 2024, ni wọn ti kede Longe.

Atẹjade naa ṣalaye pe wọn yan AIG Yetunde Longe si ipo ti obinrin ko dimu ri ninu iṣẹ ọlọpaa nilẹ Naijiria, ko le baa di alafo awọn ibi ti wọn ti n fọwọ rọ obinrin sẹyin.

Ta a ni Yetunde Longe?

AIG Yetunde Longe kẹkọọ gboye ninu imọ nipa ewu to wa fawọn eeyan ti wọn ba n lo nnkan oloro bii kẹmika (Toxicology).

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 1990, ni Yetunde Longe darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria gẹgẹ bii Cadet ASP. (Assistant Superintendent of Police).

Nipasẹ ogidi iṣẹ to n ṣe ninu iṣẹ agbofinro, Longe bẹrẹ si i gunke agba lẹnu iṣẹ naa.

AIG Longe Yetunde ti figba kan jẹ Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ati Bauchi.

Bakan naa lo ṣe kọmiṣanna lẹkan, to n ri si papakọ ofurufu ati amojuto aabo awọn ọlọpaa ni Port Harcourt.

Yetunde Longe ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba ọlọpaa patapata lẹka to n ri si ẹkọṣẹ ati idagbasoke awọn ọlọpaa l’Abuja.

Akinkanju obinrin to fi ẹkọ rẹ tukọ gbogbo ẹka to ti di mu ri ni Yetunde Longe bi IGP Kayode Egbetokun ṣe ṣapejuwe rẹ.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa Naijiria ṣalaye pe iyansipo yii yoo jẹ iwuri fun awọn obinrin ọlọpaa yooku.

Ti wọn yoo fi tun mura siṣẹ, ti yoo si ye wọn pe ko sipo ti wọn ko le dimu gẹgẹ bo ṣe ri fawọn ọkunrin ninu iṣẹ ọba.

Ọga Agba ọlọpaa sọ pe, awọn ẹkọ agba nipa iṣẹ ọlọpaa (professional courses) tun jẹ opo kan to ran Yetunde lọwọ lati gunke agba.