Ẹ wo àwọn ìlànà tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún fún ìjọba lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù

Oríṣun àwòrán, Getty
Lẹyin ti ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ati TUC ti kede pe awọn ti so iyanṣẹlodi to waye nibẹrẹ ọsẹ yii rọ, igbagbọ araalu ni pe wọn ti jọ fẹnuko sibi kan lori owo oṣu oṣiṣẹ to fa iyanṣẹlodi ọhun.
Ṣugbọn lẹyin ipade ti awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa ti iyanṣẹlodi fi dawọ duro, wọnyii ni awọn ohun ti wọn fẹnuko si nibi ipade naa:
- Ẹgbẹ oṣiṣẹ faaye silẹ lati ni ajọsọ pẹlu ijọba ti wọn yoo fi san ju 60,000 ti wọn fẹẹ san lọ.
- Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni kijọba ge oṣu meji ti wọn n beere fun lati yanju ọrọ yii ku si ọsẹ kan pere.
- Wọn lawọn gba lati so iyanṣẹlodi naa rọ ki ajọsọ tuntun le waye ni.
- Wọn ni bijọba ba kuna lati yanju ọrọ yii laarin ọsẹ kan naa, awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi alaini gbedeke pada lọwọ kan ni.
Éèló gan-an lowó oṣù tó yẹ kíjọba san fún òṣìṣẹ́ tí owó rẹ̀ kéré jù lọ?

Oríṣun àwòrán, Others
Gẹgẹ bi onimọ nipa ọrọ aje kan, Shaibu Idris, ṣe ṣalaye, o ni laarin ẹgbẹrun lọna ọgọrin (80,000), si ọgọrun-un (100,000) ati ẹgbẹrun lọna ọgọfa (120,000) lo yẹ ki oṣiṣẹ ja fun bii owo oṣu to kere julọ.
Shaibu sọ pe eyi ki i ṣe fun oṣiṣẹ ijọba nikan, awọn ẹka aladaani naa yẹ ki wọn san iru owo yii fun oṣiṣẹ ti owo rẹ kere julọ.
O ni eyi yoo ṣe e san fun awọn ileeṣẹ, ko si ni i ko ipalara ba wọn.
Onimọ nipa ọrọ aje naa ṣalaye pe 494,000 naira ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere yii han gbangba pe ko le ṣee ṣe.
O ni ko daju pe ileeṣẹ kankan le san iru owo bẹẹ ni Naijiria yii.
O ni afikun owo oṣu paapaa ko le tan iṣoro ọrọ aje Naijiria fun igba pipẹ.
Shaibu sọ pe aṣẹṣẹbẹrẹ si i gba owo tuntun leeyan n mọ ọ lara, to ba ti n pe bii oṣu meloo lẹyin rẹ, bii pe owo atijọ leeyan n gba naa ni yoo tun ri.
‘’O yẹ ki a wo bi ọrọ aje wa ṣe n gbooro si, o yẹ ka wo bi a ṣe n pese nnkan si ati eto ọgbin wa.
‘’Afikun owo oṣu yoo wulẹ mu aye dẹrun diẹ fun alaini ni, nitori ko si bi aye mẹkunnu yoo ṣe daa tan raurau bi wọn ko ba ni ohun tawọn naa n ṣe to n mowo wọle fun orilẹ-ede.
‘’A gbọdọ mura si ipese awọn nnkan (manufacturing) lorilẹ-ede yii ju ti tẹlẹ lọ.’’
Shuiabu Idris sọ pe ohun tawọn ọmọ Naijiria n fi ọwọ wọn ṣe fun idagbasoke ọrọ aje kere si ohun ti awọn ọmọ Ghana n ṣe lorilẹ-ede tiwọn.
Bẹẹ lo ni awọn ilẹ Adulawọ mi-in tun n gbiyanju lẹka yii ju Naijiria lọ.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn, àmọ́...

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kede pe awọn ti fi opin si iyanṣẹlodi alainigbedeke ti wọn n ṣe lọwọ.
Ọjọ aje ni iyanṣẹlodi ọhun bẹrẹ, lẹyin ti ijiroro laarin awọn oṣiṣẹ ati ijọba ko so eso rere, lori owo oṣu tuntun.
Iyanṣẹlodi naa mu ki ẹka ọrọ aje, ilera, irinna ọkọ ofurufu, ẹkọ, ati awọn miran dẹnukọlẹ.
Ni alẹ ọjọ Aje ni ijọba apapọ kede pe oun ti gba lati san ju ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira ti oun n dunadura rẹ tẹlẹ.
Eyi waye nibi ipademọtun ti wọn ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lọjọ Aje.
Amọ igbimọ kan yoo ṣi jiroro fun ọsẹ kan gbako, lati fẹnuko lori iye owo ti yoo tẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹ lọrun.
Lẹyin ti ijọba kede, ni ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe iyanṣẹlodi ṣi n tẹsiwaju, titi di igba ti awọn ba gbọ lati oniruuru ẹka wọn, ti wọn si pe ipade pajawiri ni owurọ ọjọ Isẹgun.
Amọ nigba ti yoo fi to wakati diẹ lẹyin ikede wọn akọkọ, ni iroyin miran tun jade pe, wọn ti fi opin si iyanṣẹlodi ọhun fun ọjọ marun-un.
A ṣi n ṣe akojọpọ̀ iroyin yii lọwọ. Ẹ ma a yẹ oju opo yii wo fun bi iroyin naa ba ṣe n kun si i












