Olóòtú ìjọba India, Narendra Modi jáwé olúborí nínú ìdìbò fún sáà kéta

Oríṣun àwòrán, getty images
Olootu ijọba orilẹede India, Narendra Modi, ti jawe olubori ninu eto idibo to waye nilẹ naa fun saa kẹta.
Eyii n tumọ si pe Modi ni yoo tẹsiwaju saa rẹ gẹgẹ bii olootu ijọba India, eyii to jẹ ipo to ti dimu lati ọdun 2014.
Nigba to n sọrọ lẹyin ikede rẹ, Modi sọ pe oun yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ikawọ oun lati ri daju pe iwa ajẹbanu dopin nilẹ naa.
O ni lootọ ni o ṣoro lati gbogun ti iwa ajẹbanu amọ oun yoo ṣe “gbogbo ohun to yẹ ni ṣiṣe lati sọ iwa ibajẹ di ohun igbagbe” ni saa kẹta yii.
Modi tun sọ pe oun yoo ggbogun ti oṣi ati iṣe lawujọ.
O sọ siwaju si pe ẹgbẹ oṣelu oun ti ṣe awọn aṣeyọri kan lati mu ọpọ araalu kuro ninu iya, ṣugbọn o ku ni ibọn n ro.
Olootu ijọba ọhun sọ pe oun yoo ri daju pe gbogbo awọn to wa ni kọrọkọndu ẹlẹkunjẹkun lo ri ọwọ ijọba oun ni saa tuntun yii.
Modi ni “a ko ni sinmi titi ti a o fi le oṣi ati iṣe kuro lorilẹede wa.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ijọba oun yoo fun awọn obinrin lanfani lati lẹnulọrọ lawujọ, oun yoo si gbiyanju ki gbogbo araalu le wa ni igbayegbadun.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn oludibo to fun oun lanfani lati tun sin India lẹekan si.















